Nitori iyanṣẹlodi ASUU, awọn akẹkọọ Fasiti Ibadan fẹhonu han

Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi iyanṣẹlodi ti awọn olukọ fasiti kaakiri orileede yii, Academic Staff Union of Nigerian Universities (ASUU), to n lọ lọwọ ti ṣe wọ oṣu mẹta, awọn akẹkọọ ile-ẹkọ giga Ibadan, University of Ibadan, fẹhonu han lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Keji, ọdun 2022 yii, lẹgbẹ awọn olukọ jake-jado fasiti gbogbo to jẹ tijọba nilẹ yii bẹrẹ iyanṣẹlodi, wọn ni ijọba kuna lati mu adehun to ba ẹgbẹ awọn ṣe lati ọdun 2009 ṣẹ.
Iyanṣẹlodi ranpẹ ni wọn kọkọ bẹrẹ nigba náà, afi bi wọn tun ṣe fi ọsẹ mejila kun kinni naa bayii.
Bi igbesẹ yii ti ṣe n ṣakoba fun eto ẹkọ lorileede yii, ati bo ṣe jẹ pe jijokoo kalẹ sile ti su awọn akẹkọọ, lo mu wọn rọ ijọba ati ẹgbẹ ASUU lati tete yanju ede aiyede to wa laarin wọn, ki wọn le pada sẹnu ẹkọ awọn kiakia.
Ṣugbọn bi ẹbẹ awọn akẹkọọ wọnyi ko ṣe wọ ijọba leti ti mu ki wọn rọ jade sigboro laaarọ Furaidee lati fẹhonu han lori bi iwoṣẹniran ọhun ko ṣe ti i pari.
Ninu ọgba Fasiti Ibadan ni wọn ti kọkọ bẹrẹ kinni naa pẹlu bi wọn ṣe di ẹnu ọna abawọle ileewe naa, ti awọn nnkan irinṣẹ ko si rọna ba ibẹ kọja.

Lẹyin naa ni wọn gbe iwọde alaafia ọhun wọ inu igboro Ibadan lọ, wọn si de awọn agbegbe bii Samọnda, Sango, Mọkọla, ati bẹẹ bẹẹ lọ pẹlu ọpọlọpọ paali ti wọn kọ oriṣiiriṣii akọle ifẹhonu han si lọwọ.
Ọkan ninu awọn akẹkọọ ọhun, Solomon Ẹmiọla, sọ pe “awọn adari wa n fi ọjọ iwaju wa tafala. Asiko si ti to bayii fun awa akẹkọọ naa lati jẹ ki wọn mọ pe a ko le fara da a mọ.”
O waa rọ ijọba ati ẹgbẹ ASUU lati jọ fikunlukun, ki iyanṣẹlodi ọhun le wa sopin kiakia.

Leave a Reply