Nitori iyansẹlodi ASUU, awọn akẹkọọ Fasiti Ilọrin sewọde ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn akẹkọọ ileewe giga Fasiti Ilọrin, nipinlẹ Kwara, sewọde alaafia, ti wọn si n fi ẹdun ọkan wọn han lori iyanṣẹlodi ASUU to n lọ lọwọ.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Ọgbẹni Taofik Waliu, to ba awọn akọrin sọrọ lorukọ akẹkọọ yooku sọ pe, wọn n ṣe iwọde yii lati jẹ ki gbogbo awọn alẹnu lọrọ ati awọn araalu lapapọ mọ bi ibanujẹ ṣe gba ọkan wọn lori iyansẹlodi ASUU, ti ọrọ naa si ti su awọn akẹkọọ patapata.
O tẹsiwaju pe awọn fẹẹ tete pari eto ẹkọ wọn ki ijọba apapọ da ASUU loun ohun ti wọn n beere fun, ki wọn le jẹ ki eto ẹkọ tẹsiwaju, ki awọn ọmọ ileewe yee fẹsẹ gbalẹ kiri adugbo. O fi kun un pe bi ipade ASUU ati ijọba apapọ ko ba ṣeso rere lọsẹ yii, awọn yoo tu jade lọpọ yanturu, tawọn yoo si di gbogbo opopona to ṣe pataki laarin igboro Ilọrin, bii ile-ijọba ipinlẹ Kwara, ile-aṣofin, olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, papakọ ofurufu ilu Ilọrin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Alaga ẹgbẹ akẹkọọ nipinlẹ Kwara, ( National Association of Nigerian Students (NANS), Ọgbẹni Salman Yusuf Yisa, rọ gomina ipinlẹ Kwara ko da si ọrọ iyẹnsẹlodi ọhun, tori pe o ti kọja agbara ijọba apapọ nikan, o tẹsiwaju pe ṣe ni awọn akẹkọọ atawọn lanlọọdu ti n ja bayii latari pe owo ile ti jo tan, tawọn o si ti i pari saa ikẹkọ kan, tawọn o si ri firifiri pe ẹgbẹ ASUU yoo wọle pada bayii.

Leave a Reply