Nitori Jẹgẹdẹ, ẹgbẹ PDP kọju ija sira wọn l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan-o-jọkan oko ọrọ lawọn asaaju PDP ipinlẹ Ondo n sọ lu ara wọn bayii latari bi ẹgbẹ wọn ṣe fidi rẹmi ninu eto idibo gomina to waye lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun to kọja.

Bo tilẹ jẹ pe o ti le loṣu mẹta daadaa ti wọn to ṣeto idibo naa sẹyin, sibẹ, ija ajaku-akata lawọn ọmọ ẹgbẹ n ba ara wọn ja, bẹẹ lawọn aṣaaju ẹgbẹ kan si n di ẹbi ifidi-rẹmi wọn le ara wọn lori.

Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo, Ọtunba Nicholas Tofowomọ, lo kọkọ bẹrẹ kinni ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to pari yii, pẹlu bo ṣe fibinu sọrọ si Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti wọn fa kalẹ gẹgẹ bii oludije wọn ninu eto idibo ọhun.

Tofowomọ ni iwa afojudi ati igberaga ti Jẹgẹdẹ hu sawọn agba ẹgbẹ kan saaju ọjọ idibo lo ṣokunfa bi ẹgbẹ awọn ko ṣe rọwọ mu.

O ni alẹ ọjọ ti agba amofin ọhun ti wọle ninu eto idibo abẹle loun ti pe e lori foonu, toun si gba a nimọran pe ko tete wa gbogbo ọna ti yoo fi so awọn ọmọ ẹgbẹ pọ sọkan, ko baa le rọrun fun un lati jawe olubori lasiko eto idibo to n bọ niwaju.

Bakan lo ni oun sọ fun un pe oun ti ṣetan lati mu un lẹyin lọ sọdọ gbogbo awọn gomina ẹgbẹ wọn lawọn ipinlẹ ti wọn ti n ṣakoso, nitori pe lọdọ wọn lo ti le rowo ti yoo fi ṣeto idibo naa gẹgẹ bo ṣe n fẹ, ṣugbọn ti Jẹgẹdẹ kọ jalẹ lati tẹle imọran ti oun fun un.

Lẹyin eyi lo ni oun tun ko awọn agbaagba ẹgbẹ lati ẹkun Guusu jọ sibi ipade kan ni Ilẹ-Oluji, ti oun si ba oludije awọn sọrọ ko waa dọbalẹ gbalaja laarin wọn ki inu gbogbo wọn ba a le yọ si i.

Loootọ lo ni Jẹgẹdẹ wa si Ilẹ-Oluji gẹgẹ bii adehun ti awọn jọ ṣe, ṣugbọn ṣe lo kọ jalẹ lati dọbalẹ fawọn agbaagba ọhun, o ni ṣe lo ṣi fila lasan, to si kuro laarin wọn.

Aṣofin ọmọ bibi Ilẹ-Oluji ọhun ni ohun ti Jẹgẹdẹ fi ba gbogbo rẹ jẹ ni ọna to fi yan igbakeji oludije rẹ.

Dipo ti iba fi fọwọsowọpọ pẹlu igbakeji Gomina, Ọnọrebu Agboọla Ajayi, atawọn agbaagba ẹgbẹ lẹkun Guusu ipinlẹ Ondo, o ni ṣe lo lọọ da ifẹ inu ara rẹ ṣe pẹlu bo ṣe fi Gboluga Ikuegboju to ti wa nibi kan tẹlẹ ṣe igbakeji ara rẹ.

Nigba to n fun agba aṣofin naa lesi ọrọ rẹ, Alukoro ẹgbẹ PDP tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Zadok Akintoye, ni ọrọ ko dun lẹnu rẹ rara nitori pe ọkan pataki lo jẹ ninu awọn to ṣiṣẹ ta ko aṣeyọri Jẹgẹdẹ saaju, ati lẹyin eto idibo naa.

O ni ki i ṣe asiko yii ti ọrọ awọn ti fẹẹ dayọ nile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo to wa l’Akurẹ lo yẹ ki sẹnetọ ọhun sẹsẹ waa maa sọ isọkusọ to n jade lẹnu rẹ.

Ọkan-o-jọkan oko ọrọ lawọn mi-in tun sọ si kọmisanna feto irinna nigba kan ri ọhun lori abuku ti wọn lo fi kan Jẹgẹdẹ.

Leave a Reply