Nitori jibiti miliọnu rẹpẹtẹ ti wọn lu, ogoji ọdun ni tọkọ-tiyawo yii yoo lo lewọn

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ẹwọn ogoji ọdún nile-ẹjọ sọ tọkọ-tiyawo kan, Ẹbiesuwa Abayọmi Frederick ati iyawo iyawo ẹ, Tinuọla Idayat Oyeginlẹ, sí nitori iwa jibiti wọn.

Onídàájọ Joyce Abdulmalik ti ile-ẹjọ gíga ijọba apapọ to wa ni Ring Road, n’Ibadan, lo gbe idajọ ọ̀hún kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Àjọ to n gbogun ti jibiti owo ati iwa magomago nilẹ yii, ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹkun Ibadan, lo gbe wọn lọ sí kootu fún ẹsun jibiti owo nla, wọn ni wọn lu obinrin oniṣowo kan to n jẹ Dunni Ọlatẹru-Ọlagbẹgi ni jibiti owo to le ni mílíọ̀nù mẹtalelaaadọta Naira (N53,713,260).

ALAROYE gbọ pe ọgbọn ẹtan lawọn tọkọ-tiyawo yii fi lu iya oniyaa ni jibiti, wọn lo nilo owo nla lati gba ẹ̀mí ẹ̀ là lọwọ iku ojiji ni, owo ọ̀hùn lawọn yóò sì fi ra awọn eroja lati ré iku ojiji to n rọ dìrọ̀dìrọ̀ lori ẹ̀ danu.

Gẹgẹ bí Ọgbẹni Wilson Uwujaren ti i ṣe Alukoro ajọ EFCC se sọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ́ sawọn oniroyin n’Ibadan, ninu oṣù karun-un ọdún 2013 lAbilekọ Dunni kọ pade awọn onijibiti naa ninu ọkọ tasin to wọ̀ nigboro Ibadan.

Ohun ti wọn fi wọle sí i lara lọrọ nipa owo dọ́là rẹpẹtẹ kan ti wọn sọ pe ọkan ninu awọn gbé sí ẹyin buutu ọkọ̀ naa, awọn sí nilo alagbara to le ba oògùn ara owo naa jẹ nitori owo ọ̀hún kò tí ì ṣe é ná pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ẹ̀mí òkùnkùn pọ ninu ẹ̀ dọ́ba.

Eyi to mu aba wa ninu wọn pe oun ni agbara ti yóò mu awọn ẹmi okunkun kuro lara owo, naa lo ríran èké sí Abilékọ Dunni, pe iku n rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lori ẹ̀, bi ko ba sì fẹẹ ku, afi ko wa owo nla wa lati fi gbẹ̀mí ẹ̀ là.

Ni gbogbo asiko yii, mílíọ̀nù mẹsan-an lowo ti Dunni ni nileefowopamọ, gbogbo ẹ̀ lo fi ranṣẹ sí Idayat ti i ṣe obinrin ninu àwọn onijibiti naa.

Síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò fi iya yii lọrun silẹ, afigba to ta gbogbo eyi to nilaari ninu awọn dukia ẹ̀, tó sì kó gbogbo owo to pa lori wọn fún àwọn onijibiti wọnyi. Ìyẹn ni gbogbo owo to padanu sọwọ wọn fi lè láàádọ́ta mílíọ̀nù Naira.

Nigba ti ko sí dukia kankan fún ìyá oníṣòwò yii lójú ẹ̀ ṣẹṣẹ waa la pe jibiti lọkọ atiyawo naa lù oun. N lo ba mu ẹjọ awọn abatẹnijẹ tọ àjọ EFCC n’Ibadan lọ.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ lajọ EFCC fi kan wọn ni kootu. Kò sì sí èyí tí wọn mórí bọ́ ninu awọn esun naa láì jẹ̀bi. Iṣiro ẹwọn ọdun mẹwaa nile-ẹjó fi ijiya ẹsun kọọkan ṣe. Ìyẹn lo ṣe jẹ pe sẹria ẹwọn ogoji (40) ọdún ladajọ da fún ẹni kọọkan wọn.

Ìyẹn nikan kọ, ileetura kan to n jẹ Victoria East Park Hotel and Suit ni Fredrick fi owo jibiti ọ̀hún kọ sigboro Ibadan, Onídàájọ Abdulmalik si ti pàṣẹ pé kí wọn lu ileetura ọhún ta ni gbanjo, ki wọn da owo to fọgbón jibiti gba lọwọ Abilékọ Dunni pada fún ùn. Eyi to ba ṣẹ́kù ninu ẹ, ki wọn san an sinu aṣunwọn ijọba apapọ orileede yii.

 

Leave a Reply