Nitori jibiti ti wọn lu awọn onibaara wọn, ileeṣẹ RevolutionPlus Property ko Toyin Abraham, Ọdunlade Adekọla si wahala

Jọkẹ Amọri

Bawọn oṣere ilẹ wa meji yii, Ọdunlade Adekọla ati Toyin Ahimaku ko ba tete wa nnkan ṣe si i, afaimọ ki ileeṣẹ to n ta ile ati ilẹ ti wọn n ṣe aṣoju fun, RevolutionPlus Property to jẹ ti Oloye Bamidele Ọnalaja ati iyawo rẹ, Tolu Ọnalaja, ma ba orukọ wọn jẹ lọdọ awọn to fẹran wọn. Eyi ko ṣeyin bi ṣe fi ẹsun jibiti kan ileeṣẹ to n ta ile ati ilẹ yii. Wọn ni wọn gbowo lọwọ ogunlọgọ eeyan lati ta ilẹ fun wọn, ṣugbọn wọn ko mu adehun ṣe lori rẹ.

Akọroyin ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni gistlovers lo kọkọ tu aṣiri naa sita, nibi to ti bu Toyin Abraham ati Ọdunlade ti wọn jẹ aṣoju ileeṣẹ naa, to si rọ wọn ki wọn wa nnkan ṣe si ọrọ ileeṣẹ ti wọn n ṣoju fun ọhun.

O ni ọpọ eeyan ni wọn n fi atẹranṣẹ ṣọwọ soun, ti wọn n sunkun pe awọn sanwo ilẹ fun RevolutionPlus Property, sugbọn wọn ko fun awọn nilẹ. Awọn mi-in wa to jẹ pe lati ọdun 2019 ni wọn ti sanwo ti wọn ko si gburoo nnkan kan titi di ba a ṣe n sọ yii.

Ọpọ awọn ti wọn si ni awọn ko ra ilẹ mọ, ki RevolutionPlus Property bawọn kowo awọn, wọn ni ileeṣẹ naa ni awọn yoo yọ ida ogoji ninu owo ti wọn ti san kalẹ.

Eyi to buru ju ninu ọrọ naa ni ede abuku ti wọn ni ọakn ninu awọn ọga ileeṣẹ naa, Tolu Ọnalaja ti wọn ni o n rọjo eebu le awọn onibaara to sanwo lori, to si n sọrọ kobakungbe si wọn.

Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe asiko niyi fun Toyin Abraham lati jade, ko gbeja awọn eeyan rẹ, ko si ri i pe oun ṣọna bi wọn ṣe maa ri owo wọn gba nitori ọun ti awọn ololufẹ rẹ ri gẹgẹ bii aṣoju ileeṣẹ naa lo mu ki wọn ra ilẹ lọwọ wọn.

Toyin Abraham naa ti jade o, o si ti rọ awọn eeyan pe ki wọn ni suuru, o ṣeleri pe gbogbo ọrọ naa lawọn yoo yanju.

Leave a Reply