Nitori kanifa, awọn janduku ba ọpọlọpọ dukia jẹ l’Adewọle, n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Bo tilẹ jẹ pe ọwọ ti tẹ diẹ lara awọn janduku kan to da wahala silẹ laduugbo Adewọle, niluu Ilọrin, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, nitori bawọn agbofinro ko ṣe gba awọn ọdọ laaye lati ṣe ayẹyẹ kanifa, sibẹ inu ibẹru lawọn araadugbo naa ṣi n gbe.

ALAROYE gbọ pe ilu Eko ni ọpọlọpọ awọn bọọsi to sọ ara wọn di janduku yii ti wa, kanifa yii gan-an lo gbe wọn wa siluu Ilọrin.

Wọn ni awọn olori adugbo naa pẹlu awọn agbofinro ko fọwọ si ayẹyẹ tawọn ọdọ fẹẹ ṣe yii, nitori pe ijọba ti ṣe ofin to ta ko ṣiṣe iru nnkan bẹẹ ati kiko ero jọ.

Ṣugbọn kinni ọhun ko dun mọ awọn ọdọ ọhun ninu, ni wọn ba gbe ayẹyẹ naa lọ si ile-itura kan to wa l’Adewọle, niluu Ilọrin.

Ohun ta a gbọ ni pe lẹyin ti wọn ṣe kanifa naa tan nile itura ni wọn bẹrẹ si i kọ lu araalu, gbogbo ohun ti wọn ba ri ni wọn n bajẹ. Bi wọn ṣe fọ gilaasi ile ni wọn fọ ti mọto. Ile awọn to n ṣe akoso aabo adugbo ta a mọ si ‘Community Police’ la gbọ pe wọn kanlẹ doju kọ.

Akọroyin wa gbọ pe ṣe lawọn janduku ọhun yinbọn soke lati dẹruba araadugbo, pẹlu aake, ada, afọku igo ni wọn fi n ba nnkan jẹ.

Alaga adugbo naa, Mallam Taiye Olobi, ni ohun to ṣẹlẹ naa ba ni lọkan jẹ gidi. O ni awọn araadugbo ti n wa ọna lati le awọn janduku ọhun danu.

O gba awọn obi nimọran lati mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn ṣọra fun mimu oogun oloro atawọn imukumu to le maa mu wọn ṣiwa-hu lawujọ.

O rọ gbogbo araadugbo lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn adari ilu lati kẹsẹ awọn janduku naa kuro nilẹ.

Ijọba gbe igbimọ oluwadii kalẹ lori wahala ipo ọba ilu Gana ati Ganmọ

Leave a Reply