Nitori kawọn oṣiṣẹ le gba kaadi idibo, ijọba Kwara kede ọjọ Ẹti ni isinmi lẹnu iṣẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lati ri i pe gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Kwara ti wọn ti to lati dibo gba kaadi idibo alalopẹ wọn, paapaa ju lọ awọn oṣiṣẹ ijọba, ni imurasilẹ de ibo ọdun to n bọ, Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Eyi lo ni yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ijọba raaye ṣe iforukọsilẹ, ki wọn si gba kaadi idibo alalopẹ wọn ko too di ọjọ ti ijọba apapọ fi gbedeke le pe yoo pari, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu Keje, ta a wa yii.

Akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, sọ eleyii ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti dari gbogbo oṣisẹ pata nipinlẹ naa lati tete lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn lọjọ Ẹti, ki wọn le se ojuṣe wọn lasiko idibo gbogboo ti yoo waye lọdun to n bọ.

 

Leave a Reply