Faith Adebọla, Eko
Ijọba apapọ ti gba awọn ẹlẹsin Kristẹni nimọran pe tori arun korona, ki wọn yẹra fun ikorajọ to maa n waye nibi orin alẹ aisun ọdun Keresimesi, eyi ti wọn n pe ni Christmas Carol, lọdun yii.
Aṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni ajọ to n ri si idena arun korona nilẹ wa sọrọ naa pẹlu awọn oniroyin l’Abuja, ibẹ ni ọga agba ajọ naa, Dokita Chikwe Ihekweazu, ti sọrọ ọhun.
Dokita Chikwe ni ọpọ awọn ikorajọ ati ajọṣe to maa n waye niru asiko yii lọdọọdun, ibaa jẹ orin aisun alẹ Keresi, ajọdun, irinajo, ipade mọlẹbi, ko seyii ti ko le mu ki arankalẹ arun korona tun burẹkẹ lojiji, ti yoo si di wahala lati kapa.
O lo yẹ ka ranti pe arun korona ko ti i kasẹ nilẹ patapata lagbaaye titi kan orileede Naijiria, kaka bẹẹ, niṣe larun naa tun n pọ si i lẹẹkeji lawọn apa ibi kan lagbaaye, tori naa, ko yẹ ka ṣọdun gbagbe ipo ta a wa.
Chikwe ni o yẹ ki kaluku wa ṣọra, paapaa awọn ẹlẹsin Kristẹni, ki korona ma baa pọ ṣi i lasiko ọdun Keresi ati lẹyin ẹ, tori ọpọ awọn arinrinajo kari-aye lo maa n lọ lati orileede kan si omi-in, boya lati ṣọdun pẹlu awọn mọlẹbi ati ọrẹ wọn, o si tun le jẹ irinajo igbafẹ.
Ni bayii, aropọ eeyan to ti lugbadi arun koro ni Naijiria ti fẹrẹ to ẹgbẹrun mejidinlaaadọrin (67,580)