Nitori Korona, gomina Eko sun iwọle awọn oṣiṣẹ siwaju

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjidinlogun, oṣu yii, lawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ti n gbaradi lati bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi ijọba ṣe paṣẹ tẹlẹ, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii pẹlu bi wọn tun ṣe sun iwọle wọn si ọjọ ki-in-ni, oṣu keji, ọdun yii.

Gomina Babajide Sanwo-Olu lo paṣẹ ayipada ọhun gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade kan ti Olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, fi sode lọjọ Abamẹta, Satide yii, lorukọ gomina.

Gomina ni ayipada naa pọn dandan lati pa aabo awọn oṣiṣẹ mọ, kijọba si le tubọ ṣe awọn nnkan to yẹ loju ọna ati kapa itankalẹ arun aṣekupani Koronafairọọsi to n fojoojumọ fẹju si i nipinlẹ Eko lẹẹkeji bayii.

Bo ṣe wa tẹlẹ, atẹjade naa ni kawọn oṣiṣẹ to wa nipele ki-in-ni si ikẹrinla maa tile ṣiṣẹ wọn lasiko yii, ki wọn si maa ṣamulo intanẹẹti lati fi i ranṣẹ bo ṣe yẹ.

Amọ ṣa o, awọn oṣiṣẹ to wa nipele kẹẹẹdogun soke, atawọn ti iṣẹ wọn jẹ aigbọdọ-ma-ṣe, bii awọn oṣiṣẹ eleto ilera, tabi ti kolẹ-kodọti ati bẹẹ bẹẹ lọ gbọdọ wa lẹnu iṣẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn gbọdọ tẹle gbogbo eewọ ati alakalẹ ijọba lori idena arankalẹ arun Korona, wọn ni ọrọ wiwọ ibomu nigba gbogbo ki i ṣe teeyan ba fẹ o, dandan ni.

Atẹjade naa pari pẹlu ikilọ pe kẹnikẹni ti ko ba ni ohunkohun to jẹ pajawiri lati ṣe nita yaa fidi mọle lasiko yii, ki kaluku si ṣọra fun ifarakinra pẹlu awọn ero, tori ewu Korona.

Leave a Reply