Nitori Korona: Ijọ Ridiimu fagi le isin aisun-ọdun tuntun

Jide Alabi

Ijọ Ridiimu ti sọ pe ko ni i si anfaani lati kora jọ papọ ṣe isin aṣekagba ti wọn maa n ṣe wọnu ọdun tuntun ni gbogbo ọjọ to ba kẹyin ninu ọdun ni gbogbo ileejọsin wọn kaakiri orilẹ-ede yii.

Ohun ti ile ijọsin yii sọ pe o faa ko ju bi wahala arun Koronafairọọsi ṣe tun bẹ silẹ lẹẹkan si i. Bẹẹ ni ijọ yii ti sọ pe o ṣẹ pataki lati tẹle ilana ti ijọba la kalẹ lati gbogun ti itankanlẹ arun buruku naa.

Bi ọjọ Ẹti, iyẹn Furaidee, ọsẹ yii, ṣe jẹ ọjọ kin-in-ni, ninu ọdun tuntun to yẹ ki isin akọkọ waye gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe e ninu ijọ naa loṣooṣu, awọn alaṣe ile-ijọsin naa ti sọ pe ti Furaidee, ọsẹ yii, ko ni i le waye nita gbangba, ati pe ori tẹlifiṣan Dove, lawọn ọmọ ijọ naa yoo ti maa ba eto ọhun lọ.

Ninu ikede ti wọn fi sita ni wọn ti gba awọn olujọsin gbogbo niyanju lati wo eto ọhun lori ẹrọ amohunmaworan Dove television, nibi ti Pasitọ Enoch Adeboye yoo ti sọ awọn ọrọ kan to ni i ṣe pẹlu ipari ọdun atawọn eto tuntun fọdun 2021.

Leave a Reply