Pẹlu bi arun asekupani Korona ṣe ti tun pada de bayii, to si n fojoojumọ gbilẹ si i, ijọba apapọ ti kede pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn wa ni ipele kejila sisalẹ jokoo sile wọn fun odidi ọsẹ marun-un, bẹẹ ni wọn ni iwọle awọn akẹkọọ di ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.
Bakan naa nijọba ti tun fofin de awọn ile igbafẹ kaakiri, bẹẹ ni wọn tun sọ pe ipejọpọ awọn ẹlẹsin ko gbọdọ kọja aadọta eeyan lẹẹkan ṣoṣo.
Alaga igbimọ amuni-fọba tileeṣẹ Aarẹ gbe kalẹ, (Presidential Task Force), Boss Mustapha, lo sọ eyi di mimọ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja.
O ni ni ibamu pẹlu aṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari fun awọn, o ti di ojuṣe aw2ọn bayii lati ri i pe ọwọja arun naa ko tan kalẹ mọ. Lati dẹkun eyi ni awọn si fi ṣe agbekalẹ awọn ilana kan ti awọn araalu yoo maa tẹle.
Lara ilana naa ni pe gbogbo ile ọti, ile faaji, ibi igbafẹ ati awọn ibi ti wọn n lo fun ayẹyẹ gbọdọ di titi.
Gbogbo awọn ile ounjẹ lo gbọdọ wa ni titi pa, yatọ si awọn ti wọn n ṣiṣẹ akanṣe bii ipese ounjẹ fun awọn oloteẹli tabi awọn ti wọn n lọọ gbe ounjẹ fun awọn eeyan nile. Ko gbọdọ si a n wọle ounjẹ lọọ jẹun lawọn ile ounjẹ igbalode.
Gbogbo awọn ayẹyẹ bii igbeyawo, ipade, idanilẹkọọ, ijọsin ati apejẹ ko gbọdọ ju aadọta eeyan lọ lẹẹkan naa.
Ki awọn ijọ ẹlẹsin ri i pe wọn bọwọ fun ofin imọtoto, ki wọn si ri i pe awọn eeyan takete sira wọn. Nibi to ba ti pọn dandan lati gba awọn eeyan to ju aadọta lọ laaye, iru eto bẹẹ gbọdọ waye ni ita gbangba.
Awọn awakọ paapaa ko gbọdọ gbe ju ilaji iye ero ti ọkọ wọn le gba lọ lati jẹ ki awọn ti wọn gbe le jinna sira wọn.