Stephen Ajagbe, Ilorin
Lọna ati dẹkun itankalẹ arun Koronafairọọsi, ijọba ipinlẹ Kwara ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ rẹ lati jokoo sile wọn, bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Awọn tiṣẹ wọn ṣe pataki ju bii oṣiṣẹ eto ilera ati bẹẹ lọ nikan lo gbọdọ lọ sibi iṣẹ.
Bakan naa ni wọn tun fofin de ile-ijo, ayẹyẹ ilu ati awọn ile-ijọsin.
Kọmiṣanna feto ilera, Dokita Raji Razak, to ṣoju Igbakeji Gomina Kwara, Kayọde Alabi, lo ka awọn ilana tuntun naa fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
O ni lati akoko yii lọ, o ti di dandan fun gbogbo eeyan lati maa lo ibomu, ẹni to ba tapa sofin yii yoo rugi oyin.
Bakan naa lo ni awọn ile-ijọsin gbọdọ din ero to n jọsin lẹẹkan ṣoṣo ku pẹlu ida aadọta lati faaye gba titakete sira wọn.
Ijọba tun ni gbogbo ipejọpọ yoowu, yala igbeyawo, ipade, apejẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ko gbọdọ ju aadọta eeyan lọ.
Lara ofin Covid-19 tuntun naa ni pe ko gbọdọ si irin laarin aago mejila alẹ titi wọ aago mẹrin aabọ owurọ, ki onikaluku gbele rẹ laarin awọn wakati naa.
Ijọba tun ni awọn onimọto ero gbọdọ tẹle ofin gbigbe ero niwọnba, ki wọn si ri i pe awọn ero inu ọkọ lo ibomu.
Bakan naa, ijọba ti lawọn yoo kede ọjọ iwọle awọn ọmọleewe, ṣugbọn ni bayii na, ki wọn ṣi maa gbele, ki awọn ileewe ṣi wa ni titi.