Nitori Korona, ijọba fofin de kanifa ati ipejọpọ rẹpẹtẹ l’ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Pẹlu bi Korona tawọn eeyan ro pe o ti lọ tẹlẹ ṣe tun ti n ṣọṣẹ lorilẹ-ede yii, ijọba ipinlẹ Ogun ti fofin de ayẹyẹ ipari ọdun bii kanifa ati pati ti wọn fi n wọ ọdun tuntun to le mu Korona pọ si i.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, sọ eyi di mimọ lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin.

Yatọ si kanifa, ofin ti de apejọpọ ileejọsin to ba kọja eeyan aadọta (50). Awọn ile ọti, ile faaji gbogbo gbọdọ wa ni titi pa titi digba tijọba yoo fi ri i pe wọn ti ṣee ṣi pada. Bakan naa ni awọn akẹkọọ gbọdọ wa nile titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.

Ni ti awọn oṣiṣẹ ijọba, ijọba ni ki wọn lọ fun isinmi ọdun, bẹrẹ lati Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ ni Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu kin-in-ni ọdun 2021.

Awọn ọlọja le ṣilẹkun lati aago mẹjọ aarọ, gomina ni ki wọn ri i pe wọn palẹmọ laago mẹrin irọlẹ. Lawọn asiko ti wọn ba si wa lọja naa, wọn gbọdọ tẹle ofin Korona bii lilo ibomu, pipese nnkan ifọwọ ati yiyago funra ẹni.

Bakan naa ni wọn kilọ fawọn onimọto atawọn ọlọkada pe wọn ko gbọdọ gbe ero kọja alakalẹ ofin lasiko yii, eyi ti i ṣe idaji iye ero ti wọn n gbe tẹle.

Awọn ero ọkọ atẹni to n wa mọto gbọdọ lo ibomu, gẹgẹ bi ọlọkada atero to ba gbe naa ṣẹ gbọdọ lo o.

Lakootan, ijọba gba araalu nimọran lori irinajo lilọ lasiko ọdun yii, wọn lo daa ki kaluku ṣọdun nile ẹ ju ko lọọ ko Koro wale tabi ko lọọ ko tiẹ ba wọn nibi to ba gbe ọdun lọ.

Leave a Reply