Nitori Korona, Sanwo-Olu sun iwọle awọn oṣiṣẹ siwaju

Faith Adebọla, Eko

 Ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ni ijọba Eko sun iwọle awọn oṣiṣẹ ọba ti wọn wa nipele kẹrinla sisalẹ si bayii. Atẹjade ti Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, gbe jade lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lorukọ gomina lo fidi eyi mulẹ.

Atẹjade naa sọ pe sọ pe, yatọ sawọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn jẹ aigbọdọmaṣe, to si pọn dandan fun lati jade, o ni kawọn to ku lati ipele kin-in-ni si ikẹrinla maa ṣiṣẹ wọn lati ile, ki wọn maa lo ori atẹ ayelujara.

Gomina fi kun un pe wọn yoo maa jiroro lori awọn ipade pataki to ba yẹ ko waye latori awọn ikanni ajọlo ti wọn fi n ṣepade lori intanẹẹti.

O ni Sanwo-Olu gbe igbesẹ pataki yii lati tubọ daabo bo awọn oṣiṣẹ ọba lọwọ ajakalẹ arun Korona ti itankalẹ rẹ ti n gogo si i nipinlẹ naa.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, ni gomina naa kọkọ paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ ọba wọnyi fidi mọle fọsẹ meji na, latari bi arun naa ṣe tun n ruwe nigba naa.

Ẹyin naa ni Gomina Sanwo-Olu funra rẹ lugbadi aisan ọhun, to si ni lati wa ni igbele fun bii ọsẹ kan. Ọpẹlọpẹ awọn itọju to ri gba ni Ọlọrun fi ko o yọ.

Leave a Reply