Ọlawale Ajao, Ibadan
Wahala ti bẹ silẹ laafin Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, pẹlu bi ipade igbimọ lọbalọba Olubadan to yẹ ko waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Niṣe lawọn ọmọ igbimọ ọhun yari pe awọn ko le gba ki Ọtun Olubadan, Oloye Rashidi Adewọlu Ladọja, jokoo ṣepade pẹlu awọn.
Ipinnu awọn ọba ti Olubadan ṣẹṣẹ gbe ade le lori yii ko ṣẹyin bi Ọtun Olubadan ṣe pe ẹjọ ta ko igbega wọn sipo ọba.
Oloye Agba Ladọja lo pẹjọ ta ko Olubadan, awọn ọba to gba ade naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, ati kọmiṣanna pẹlu agbẹjọro agba nipinlẹ Ọyọ, eyi ti ẹjọ ọhun ṣi n lọ lọwọ.
Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, ẹni to jẹ Balogun ilẹ Ibadan, to si tun jẹ oloye to tẹle Olubadan, ni awọn ti pinnu pe ko sẹnikẹni ninu awọn ti yoo jokoo pọ ba Ọtun Olubadan ṣepade titi ti ẹjọ to pe yoo fi pari ni kootu. O ni owe Yoruba kan lo ni a ki i ti kootu de ṣe ọrẹ, idi niyẹn tawọn o ṣe ni i jokoo pọ pẹlu Oloye Ladọja.
Bo tilẹ jẹ pe Olubadan gbiyanju lati pẹtu si aawọ yii, ṣugbọn awọn yooku to wa nibi ipade yii ni awọn kin Ọba Ọlakulẹhin lẹyin, wọn ni eyi ti Balogun Olubadan sọ yii, niṣe lo da bii ẹni pe o gba ẹnu awọn sọrọ, nitori ohun to wa lọkan awọn gan-an lo ti sọ yẹn.
Ninu ọrọ tiẹ, Oloye Ladọja sọ pe oun ko deede wa sibi ipade naa bi ko ṣe pe wọn pe oun sibẹ.
O ṣalaye pe bo ba ṣe ipade igbimọ lọbalọba ni wọn pe ipade yii foun ni, oun iba ti wulẹ waa ba wọn kopa nibẹ, nitori Ọtun Olubadan loun jẹ, oun ko ti i jọba. Ṣugbọn
ipade igbimọ oludamọran Olubadan ni wọn pe ipade ọhun ninu lẹta ti wọn fi pe oun fun ipade, niwọn igba to si ti jẹ pe ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ Olubadan loun jẹ gẹgẹ bii ipo Ọtun Olubadan ti oun wa yii, dandan ni ki oun jẹ ipe si iru ipade bẹẹ, nigba ti oun ko ni oke mi-in lẹyin ọrun.
Ladọja sọ siwaju pe ki i ṣe pe oun ni ikusinu sẹnikankan ninu Olubadan ati eyikeyii ninu awọn ọmọ igbimọ rẹ, ipinnu ti oun ṣe loun duro le lori, ati pe oun pẹlu Olubadan ṣi n fikunlukun pọ lori ọrọ naa lọwọlọwọ.
Ṣugbọn ṣa, ipade ọhun ko le tẹsiwaju mọ, n ni wọn ba sun un siwaju lai le jiroro lori ohunkohun.
Awọn to peju sibi ipade ọhun ni Olubadan, Ọba Lekan funra ẹ; Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin ati Ọtun Olubadan, Agba-Oye Rashidi Ladọja pẹlu Ashipa Olubadan; Ashipa Balogun, to fi mọ Ẹkarun-un Olubadan.