Nitori LAUTECH, Oyetọla fọkan awọn oṣiṣẹ balẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ni bayii tijọba ipinlẹ Ọṣun ti yọnda iṣakoso Ladoke Akintọla University Teaching Hospital funjọba ipinlẹ Ọyọ, wọn ti ṣeleri pe ko si oṣiṣẹ kankan ti yoo padanu iṣẹ rẹ nipasẹ igbesẹ ọhun.

Kọmisanna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Funkẹ Ẹgbẹmọde, lo fi atẹjade naa sita lọjọ Abamẹta, Satide. O ṣalaye pe Gomina Oyetọla ko fi ọrọ awọn oṣiṣẹ ṣere rara, ko si ni i faaye gba ohunkohun ti yoo gbegi dina itẹsiwaju wọn.

Ẹgbẹmọde fi kun ọrọ rẹ pe ninu akọsilẹ adehun to wa laarin ipinlẹ mejeeji, ipinlẹ Ọyọ ko gbọdọ gba iṣẹ lọwọ oṣiṣẹ kankan, bẹẹ ni ko gbọdọ si iyapa kankan laarin awọn oṣiṣẹ to jẹ tipinlẹ Ọyọ ati ti Ọṣun.

Bakan naa lo ni ki gbogbo awọn akẹkọọ fi ọkan wọn balẹ, nitori ko si afikun owo ileewe rara, iye ti awọn akẹkọọ ti wọn jẹ tipinlẹ Ọyọ ba san naa ni awọn tipinlẹ Ọṣun gbọdọ san, ko gbọdọ si iyapa rara.

O ni gbogbo awọn nnkan ini to jẹ ti College of Health Sciences, niluu Oṣogbo, ati ti Ọsibitu Mercyland, pẹlu eyi to wa niluu Ilie ti di tijọba ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bo ṣe wa ninu adehun naa.

Ọdun 1990 ni wọn da ileewosan LAUTECH silẹ niluu Ogbomoṣọ, wọn si gbe ẹka ileewosan rẹ wa siluu Oṣogbo lẹyin idasilẹ ipinlẹ Ọṣun lọdun 1991, latigba naa si nipinlẹ mejeeji ti n gbọ bukaata lori rẹ.

Ṣugbọn lẹyin oniruuru wahala ni ajọ National Universities Commission (NUC) kede lọjọ Ẹti, Furaidee, pe kipinlẹ Ọṣun yọnda rẹ fun Ọyọ.

Leave a Reply