Nitori maaluu kan to ku, ọlọpaa ni kawọn oloye ilu Ifọn mẹrin yọju s’Abuja, lawọn araalu ba fẹhonu han

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Awọn agbaagba ilu Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, ti fẹho nu han fun bi ileesẹ ọlọpaa ṣe fiwe pe mẹrin lara wọn siluu Abuja lati waa jẹjọ ẹsun ti Fulani darandaran kan, Abdulahi, fi kan wọn lori ọkan ninu maaluu rẹ ti wọn pa.

Aarẹ ẹgbẹ idagbasoke Ifọn, Oloye Fẹmi Awani, to gba ẹnu awọn agbaagba ọhun sọrọ ni ohun to ba awọn ninu jẹ ju lọ ni bawọn ọlọpaa ṣe kuna lati mu ẹnikẹni lẹyin bii osu mẹta tawọn Fulani agbebọn ti pa Olufọn tilu Ifọn, Ọba Israel Adeusi, ṣugbọn ti wọn raaye ati fiwe pe awọn oloye nla nla mẹrin nitori maaluu kan ṣoṣo ti wọn pa.

O ni awọn mẹrẹẹrin ti wọn fiwe pe ọhun, iyẹn, Oloye Ekon, Oloye Olijewu, Ọnarebu Saliu Ọmọtọṣọ ati Ọnarebu Ọlaniyi Ẹni-Olotu to jẹ olori awọn ọdẹ ilu Ifọn ni wọn n mojuto ọrọ iṣakoso ilu lati igba ti wọn ti yinbọn pa Ọba Adeusi lagbegbe Ẹlẹgbẹka lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu kọkanla, ọdun to kọja.

Laipẹ yii lo ni wọn ran awọn ọlọpaa kan wa lati waa fi tipatipa mu awọn agbaagba ọhun ki wọn le lọọ jẹ ipe naa niluu Abuja.

O ni o ya awọn lẹnu pe ki i ṣe ọrọ maaluu kan soso ti wọn pa nikan lo wa ninu iwe ẹsun tawọn darandaran naa fi ṣọwọ si olu ileesẹ ọlọpaa l’Abuja, awọn ẹsun bii igbimọ pọ huwa to lodi sofin, didun ikooko mọ ẹmi ẹni ati gbigbiyanju ati ji ni gbe lo ni wọn fi kan awọn ti wọn fiwe pe ọhun.

Oloye Awani rọ Adamu Muhammad tó jẹ ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii lati tubọ sewadii iwe ẹsun ti Abdulahi kọ daadaa, nitori pe ọwọ tawọn ọlọpaa fi mu ọrọ maaluu tí wọn lo ku ọhun mu ifura lọwọ.

O ni o ṣee ṣe ki wọn fẹẹ fi iṣẹlẹ yii kẹwọ, ki wọn le yọnda awọn Fulani kan tọwọ tí tẹ lagbegbe Ifọn fẹsun ajinigbe silẹ.

Ọkan ninu awọn Oloye giga ilu Ifọn, Oloye Joseph Ajayi, to tun sọrọ nipa iṣẹlẹ naa ni ibi ti wọn darukọ sínú iwe ẹsun ti wọn kọ ko si lagbegbe àwọn, o ni idi to fi jẹ pe awọn agbaagba ilu ọhun ni wọn ransẹ pe lati Abuja lo si n ya awọn lẹnu.

Igba kan wa to ni wọn pe gbogbo awọn ọdẹ to wa niluu Ifọn jade, ti wọn si ni kawọn Fulani darandaran ọhun nawọ si ẹni to pa maaluu wọn, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹnikẹni tọka si.

Osu kan lẹyin eyi lo ni wọn tun ko awọn iwe ẹsun kan wa lati Abuja, ti wọn si ni kawọn maa buwọ lu u lai si orukọ awọn nibẹ.

Awọn agbaagba ilu ọhun ni nnkan itiju nla lo yẹ ko jẹ fun ileesẹ ọlọpaa lati fi awọn to pa odidi ọba alaye onipo kin-in-ni silẹ lai ri nnkan kan ṣe nipa rẹ, ki wọn si waa maa sare wa awọn ti wọn fẹsun kan pe wọn pa maaluu kan ṣoṣo kiri.

 

Leave a Reply