Nitori meji ninu wọn tibọn pa, awọn tọọgi ba ile olori Amọtẹkun jẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, la gbọ pe wahala ti bẹrẹ laarin igun awọn tọọgi meji lagbegbe Asọjẹ, ni Balogun Agoro, niluu Oṣogbo, ṣugbọn nigba ti ilẹ fi maa mọ, a gbọ pe eeyan meji ti dero ọrun.

A gbọ pe wahala emi ju ọ, iwọ o ju mi, lo fa ija naa, eleyii to si ko hilahilo ba awọn eeyan agbegbe Plantation, Gbọnmi, Ọja-Ọba ati Oluọdẹ, ninu ilu naa.

Ibinu iṣẹlẹ yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lo fa a ti awọn kan fi lọọ ba ọfiisi ajọ Amọtẹkun jẹ, eyi ko si ṣẹyin ohun ti awọn tọọgi naa n sọ pe ṣe ni awọn Amọtẹkun n le awọn pẹlu ibọn, ti ibọn si ba awọn neji laarin wọn.

Ṣugbọn ohun ti awọn Amọtẹkun n sọ ni pe lasiko ti awọn tọọgi igun mejeeji kọju ija siraa wọn ni wọn yinbọn pa ara wọn.

Ohun ti a gbọ lagbegbe naa ni pe nigba ti awọn igun tọọgi mejeeji naa bẹrẹ ija ni awọn Amọtẹkun de, ti wọn si dabọn bolẹ, lasiko naa si ni awọn meji ku, ti ẹni kan si fara pa. A gbọ pe ṣe ni wọn n gbe awọn oku naa kaakiri laaarọ ọjọ lṣẹgun, Tusidee, ko too di pe awọn ọlọpaa gba a lọwọ wọn.

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣalaye pe ṣe ni awọn fi pampẹ mu ọkan lara awọn tọọgi ti wọn n fa wahala naa nitori pe awọn ọlọpaa ti n wa awọn kan lara wọn.

O ni, “Nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Tusidee la mu ọkan lara wọn lagbegbe Balogun Agoro, niluu Oṣogbo, a si fa a le ‘ọlọpaa lọwọ. A ko yinbọn lu ẹnikankan nitori agbegbe ti ero pọ si ni, aṣita ibọn si le ba awọn araalu.
“Koda, nigba ti a n dọdẹ wọn kaakiri, awọn ọlọpaa wọ (tolled) ọkọ ọga wọn, Emir, lọ si agọ wọn.

“Ọkan lara wọn, Lekan, lo ko awọn janduuki bii ọgbọn wa sile mi, wọn lo aake lati fi ja geeti, wọn fọ gilaasi, wọn si ba awọn ọkọ kan jẹ”

Leave a Reply