Nitori ọrọ ti ko to nnkan, awọn agbofinro yinbọn mọra wọn l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ori lo ko ọlọpaa kan, Kọburu Fatai Yẹkinni, yọ lọwọ iku ojiji ninu ọdun tuntun pẹlu bi ẹgbẹ ẹ nidii iṣẹ agbofinro ṣe wo ṣunṣun, to si yinbọn fun un. Ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun, Ọgbẹni, Ibrahim Ogundele, yinbọn fun kọburu ọlọpaa naa.

Ohun ti a n wi yii kọ la ba si maa wi nipa Kọburu Yekinni bi ki i baa ṣe pe awọn ọlọpaa ẹgbẹ ẹ wa nitosi, ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa niluu naa fun itọju pajawiri.

ALAROYE gbọ pe ọrọ kan lo ṣe bii ariyanjiyan ija laarin awọn agbofinro ti wọn n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ ọtọọtọ yii laduugbo Sanga, niluu Ọyọ, ti eyi to jẹ oṣiṣẹ agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ si yinbọn fun agbofinro ijọba apapọ ti ẹṣọ Amọtẹkun naa fi yinbọn fun ọkunrin naa lẹsẹ osi.

Lasiko ti awọn ọlọpaa n gbiyanju lati tú awọn ọdọ kan ti wọn kora wọn jọ fun kánífà laduugbo Sanga ka lede aiyede bẹ silẹ laarin awọn Amọtẹkun atawọn ọlọpaa nitori ti awọn Amọtẹkun ko fẹ ki wọn di awọn ọdọ alajọdun naa lọwọ.

Ọrọ yii ni wọn n fa lọwọ ti awọn eeyan fi deede gburoo ibọn, nigba ti wọn yoo si fi ṣeju pẹu, ọkan ninu awọn ọlọpaa ni wọn n wo nilẹẹlẹ to n japoro.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti fofin de kanifa ṣiṣe jake-jado ipinlẹ yii. Nitori ẹ lawọn araalu kan to fẹran alaafia ṣe pe awọn ọlọpaa teṣan Ojongbodu, niluu Ọyọ, lati fi to wọn leti nigba ti awọn ọdọ adugbo Sanga pàtẹ ariya ní ìlòdì sofin ileeṣẹ agbofinro.

O ni lasiko ti awọn ọlọpaa n gbiyanju lati tu awọn ọdọ naa ka loṣiṣẹ Amọtẹkun yinbọn mọ ọlọpaa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ẹni to yinbọn mọ agbofinro yii ti wa lakata wa bayii fun iwadii to yẹ. Bẹẹ lọlọpaa ti wọn yinbọn mọ ṣi wa nileewosan to ti n gbatọju niluu Ọyọ.”

Leave a Reply