Nitori o ran ọkọ ẹ ti wọn fẹsun apaayan kan lọwọ lati sa lọ, Ruka dero kootu l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kootu Majisireeti to wa l’Ọta, nipinlẹ Ogun, ni iyaale ile kan torukọ ẹ n jẹ Rukayat Ibrahim ti n jẹjọ igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi bayii, nitori wọn ni oun lo ran ọkọ ẹ,  Saliu Jẹliu, lọwọ lati sa kuro l’Ọta, to sa gba Ekiti lọ.

Ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni wọn foju Ruka, ẹni ọdun marundinlogoji (35) ba ile-ẹjọ naa, ti Agbefọba, E.O Adaraloye, si ṣalaye pe ẹsun ipaniyan wa lọrun Saliu, ọkọ Ruka, nitori ẹni kan ti wọn ni o tọwọ rẹ di ero ọrun l’Ọta, ipinlẹ Ogun.

Ṣugbọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii, Ruka ṣe ọna ti ọkọ rẹ fi bọ mọ awọn to fẹẹ mu un funjọba lọwọ, Saliu si sa kuro lopopona Oloko ti wọn n gbe l’Ọta, o sa gba Ekiti lọ, nijọba ibilẹ Mọba.

Agbefọba sọ pe awọn ọlọpaa pada ri ọkọ Ruka mu l’Ekiti, nitori wọn n dọdẹ rẹ kiri ni. Paapaa nigba ti wọn ti ta awọn ọlọpaa ibẹ lolobo nipa ọdaran kan to sa ni.

Iwa ti Ruka hu yii lodi sofin gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi, abala ẹẹdẹgbẹta ati mọkandinlogun(519) lo ta ko keeyan fẹyin se afurasi lati sa lọ, ijiya to nipọn si wa fun un pẹlu.

Ṣugbọn Ruka  loun ko jẹbi ẹsun yii, nigba ti kootu beere pe ṣe o jẹbi tabi bẹẹ kọ.

Adajọ A.O Adeyẹmi faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000), pẹlu oniduuro kan niye kan naa.

O paṣẹ pe oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu, o gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ, o si gbọdọ le ṣafihan iwe-owo ori sisan rẹ fun ipinlẹ Ogun.

Igbẹjọ tun di ọjọ kẹjila, oṣu keje ọdun 2021.

Leave a Reply