Nitori Ọbasẹki, awọn ara ipinlẹ Edo ti bẹrẹ ijo loriṣiriṣi agbegbe

Aderounmu Kazeem

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede orukọ rẹ, awọn araalu ti bẹrẹ ijo kaakiri oriṣiriṣi agbegbe ni ipinlẹ Edo,nitori Gomina Godwin Obasẹki, wọn ni o ti han sawọn pe oun lo jawe olubori ninu ibo ti wọn di, ko si si jubita to le yi i pada.

Ṣe kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Edo ni ibo gomina ti waye lana-an Satide, ọjọ Abamẹta, bẹẹ ni wọn ti bẹrẹ si ka esi idibo ọhun. Iroyin to si wa nita bayii ni pe lawọn ijọba ibilẹ mẹtala ti esi ibo wọn ti wa nita, Gomina Godwin Obaseki lo n le iwaju bayii, ibo ti ẹgbẹ oṣelu ẹ ni si le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ojilelugba (240,935), nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC ni tiẹ ni ibo ẹgbẹrun lọna aadọjọ-o-le (154,192).

Ṣaaju asiko yii ni oriṣiriiṣi esi ibo ti wa nita, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa n pariwo wi pe ki awọn eeyan ma ṣe gba esi ibo ̀ọhun gbọ, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo n gbe e jade lati fidi ẹ mulẹ wi pe awọn lawọn n jawe olubori.

Ohun ti APC sọ ree o, ṣugbọn awọn ti PDP naa ti pariwo wi pe, gbogbo ọna ni APC n wa lati yi esi ibo ọhun, nitori pe awọn gan an lawọn wa loke tente ninu abajade esi ibo naa.

Lọjọ Satide lẹyin eto idibo naa ni iroyin ti wa nita wi pe ẹgbẹ oṣelu awọn oludije mejeeji ti wọn n ṣaaju ninu eto idibo ọhun, Godwin Obaseki ati Pasitọ Ize Iyamu lo wọle nibi ti kaluku wọn ti dibo.

Bẹẹ gẹgẹ ni Adams Oshiomhole, ẹni ti ṣe alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ naa ati Philip Shuaibu, ẹni ti ṣe igbakeji gomina ipinlẹ ọhun. Bakan naa ni Ogbẹni Gani Audu naa ri agbegbe tiẹ mu.

Ohun tawọn olubẹwo si sọ ni pe, ajọ INEC gbiyanju lọpọlọpọ bi gbogbo eto idibo ọhun se lọ, bo tilẹ jẹ pe awọn oloṣelu kan ko ṣai fẹhonu wọn han wi pe ajọ naa ko ṣiṣẹ wọn to, nitori kudiẹkudiẹ ti maṣinni idibo da silẹ lawọn agbegbe kan.

Adams Oshiomhole, ẹni ti ṣe alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹle, to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Edo ri naa fẹhonu ẹ han lori bi maṣinni kaadi naa ko ṣe ṣiṣẹ daadaa.

Owurọ kutu lawọn oludibo ti bẹrẹ si ni jade, bẹẹ lawọn ajọ eleto idibo paapaa, iyen INEC naa ti wa nikalẹ, ti kinni ọhun si bẹrẹ wọorọwọ.

Awọn ẹṣọ agbofinro paapaa naa ko gbẹyin o, wamu ni wọn duro, tawọn to si fẹẹ dibo paapaa ko gbagbe wi pe o ṣe pataki ki awọn tẹle ilana ofin Covid 19, ti gbogbo eto si n lọ bo ti tọ ati bo ṣe yẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ohun tawọn olubẹwo kan sọ ni pe eto idibo ọhun lọ daadaa, sibẹ gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki lo kọkọ pariwo sita, ohun to si sọ ni pe, ojooro ti n ṣẹlẹ lagbegbe oun, won ti fẹ fi eru ibo yi oun lagbo da sina.

Fun bi wakati kan ni gomina yii fi to sori ila, ti o n reti ki kaadi ibo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ. Lojuẹsẹ ti Obaseki ti lanfaani lati wa niwaju awọn oniroyin lo ti n pariwo wi pe, jakujaku ni ileeṣẹ ajọ eleto idibo ṣe, nitori pe o yẹ ki imurasilọ wọn dara ju bayii lọ, ko si yẹ ki maṣinni kaadi idibo maa ṣe segesege.

Ni deede aago mejila ku iṣẹju mejila lo too dibo.  O ni, ohun ibanujẹ nla lo jẹ fun oun lati fi wakati kan aabọ duro sori ila ki oun too ri ibo di. O ni, bii igbin ni maṣinni idibo n fa, ti ko yara rara, ati pe bo ṣe ṣẹlẹ kaakiri gboogbo ijọba ibilẹ Oredo niyẹn.

Gomina naa ko ṣai mẹnuba owo tawọn kan n pin kiri, bẹẹ lo ni iyẹn ko ba oun lẹru, nitori pe awọn eeyan Edo ko ni i ta ibo wọn. O ni, owo ti wọn ba gba, wọn yoo kan fi lanu lasan ni.

Bo tilẹ je pe ohun tawọn eeyan kan sọ ni pe wahala wa daadaa lawọn agbegbe kan lasiko idibo ọhun, sibẹ ohun ti igbakeji ọga agba ninu iṣẹ ọlọpaa, Adelẹyẹ Oyebade sọ ni pe ko si ootọ ninu iroyin to sọ pe wọn yinbọn fun ẹni kan ni Ologbo nijọba ibilẹ Ikpoba-Okha, ati pe ko si ootọ ninu eyi ti wọn sọ pe o tun ṣẹlẹ naa ni Oza nijọba ibilẹ Orhiomwon.

 

 

Leave a Reply