Nitori ọdun iṣẹmbaye ti wọn fẹẹ ṣe, Deji ti gbogbo ọja pa l’Akurẹ fun ọjọ meji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ. 

Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi, ti paṣẹ pe ki gbogbo ọja atawọn ṣọọbu to wa nigboro ilu Akurẹ wa ni titi pa fun odidi ọjọ meji latari ọdun Aheregbe ati Amọle ti wọn fẹẹ ṣe.

Michael Adeyẹye to jẹ akọwe iroyin fun Deji lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja. O ni aṣẹ yii waye ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣẹdalẹ ilu Akurẹ, eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun.

O ni gẹgẹ bi ohun tawọn agbaagba ilu fẹnu ko le lori, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu to n bọ yii, ni wọn fi awọn ọdun mejeeji yii si.

Adeyẹye ni ko ni i si ọja tita tabi rira nibikibi kaakiri ilu Akurẹ gẹgẹ bo ṣe maa n ri tẹlẹ lasiko ti wọn ba n ṣayẹyẹ ọdun mejeeji.

Yatọ si awọn ọlọja ti wọn ko gbọdọ patẹ ọja nibikibi, o ni aṣẹ naa ko di igbokegbodo awọn ọkọ ati lilọ-bibọ awọn eeyan lọwọ.

Leave a Reply