Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Afi bii ere ori itage lo ri ninu ọgba Fasiti ipinlẹ Ọṣun (Osun State University) to wa niluu Oṣogbo, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, nigba ti awọn oṣiṣẹ ile-ẹkọ naa fọn sita, ti wọn si n yọ pe ọga awọn tẹlẹ, Ọjọgbọn Labọ Popoọla, fẹyinti.
Lati ẹnu ọna ọfiisi ọga naa ni wọn ti gbalẹ titi de geeti ile-ẹkọ ọhun, pẹlu orin apara ati orin ẹgan, wọn ni Ọlọrun ti ba awọn le ‘ajẹgaba lori ẹni’ lọ.
Ọdun marun-un ni Popoọla lo ni UNIOSUN, ṣugbọn ko si irẹpọ kankan laarin oun atawọn oṣiṣẹ rara, koda, wọn gbe ara wọn dele-ẹjọ, eleyii ti ko ṣẹlẹ nibẹ ri.
Oniruuru akọle lawọn oṣiṣẹ naa gbe lọwọ, wọn n kọrin, wọn n jo, bẹẹ ni awọn kan jokoo sidii akara ti wọn n din in, ti wọn si n sọ pe awọn j’akara lati rẹyin ọta awọn.
Awọn oṣiṣẹ naa ni wọn wa labẹ Non-academic Staff Union of Educational and Associated Institutions (NASU), Senior Staff Association of Nigerian Universities (SSANU) ati National Association of Academic Technologists (NAAT).
Ohun ti gbogbo wọn n tẹnumọ ni pe asiko inira patapata gbaa ni asiko Popoọla, eyi to kun fun fifi ọwọ ọla gba ni loju, iwa ibajẹ, jẹgudujẹra, aṣilo ipo atawọn nnkan mi in.
Wọn gbe akọle nla kan si ara ọfiisi ti awọn alakooso ile-ẹkọ naa ti maa n ṣepade (Senate Building) nibẹ ni wọn si kọ ọ si pe “Pẹlu ọkan ọpẹ si Ọlọrun, gbogbo awa oṣiṣẹ Fasiti Ọṣun ṣajọyọ lilọ apọnniloju, Ọjọgbọn Labọ Popoọla.
“Lara awọn nnkan ti a oo maa ranti rẹ si ni irọ pipa, ifipa-mu-ni-sin, aṣilo agbara, igberaga, oogun ṣiṣe, tinu mi ni n oo ṣe, aifinilọkanbalẹ, iwa ibajẹ oniruuru ati bẹẹ bẹẹ lọ”
Gbogbo awọn oṣiṣẹ naa ni wọn sọ pe itura yoo pada de si Fasiti Ọṣun bayii, ti wọn si rọ adele tuntun, Ọjọgbọn Adefẹmi Bello, lati tun awọn nnkan ti Popoọla ti bajẹ ṣe.
Alaga awọn NASU, Comrade Isaiah Fayẹmi, sọ pe Popoọla lo iṣejọba ọdun marun-un rẹ lati fi ni awọn lara pupọ, o ni nigba ti awọn fẹhonu han lori iwa jẹgudujẹra to n lọ lasiko rẹ lo gbe awọn lọ si kootu.
Fayẹmi fi kun ọrọ rẹ pe lati le jẹ ẹkọ nla fun awọn ti wọn wa nipo kaakiri lawọn ṣe ṣe ajọyọ lilọ Popoọla pẹlu gbigba ẹsẹ wahala rẹ kuro ninu ọgba fasiti naa ati didin akara rẹ.