Nitori ọgọrun-un Naira, kọndọkitọ fẹṣẹ yọ eyin ero ọko Adewale Adeoye

Ile-ẹjọ Magisireeti kan to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni ọmọkunerin kan, Azeez Balogun, ti n kawọn pọnyin rojọ bayii latari pe o fẹṣẹ yọ meji ninu eyin ero to wọ mọto rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe ede-aiyede kekere kan lo bẹ silẹ laarin kọndọkitọ ọhun ati Shina Ọlanrewaju to jẹ ero inu mọto naa lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023  yii.

Wọn ni bọsitọọbu kan ti wọn n pe ni Ile-Epo, ni ero ọhun ti wọ mọto naa, to si n lọ si agbegbe Abule Ẹgba, niluu Eko kan naa. Ṣugbọn ko pẹ rara ti ija fi bẹ silẹ laarin kọndọkitọ ọhun pẹlu ero to gbe yii latari ṣenji ọgọrun-un Naira to da wọn pọ.

Oju-ẹsẹ ni kọndọkitọ ọhun fibinu wọ ero to gbe bọ silẹ ninu mọto naa silẹ, to si lu u bii baara, o tun faṣọ rẹ ya pẹrẹpẹrẹ. Nibi to ti n lu u lọwọ lo ti fi ẹṣẹ yọ meji ninu eyin ẹnu rẹ  ti ẹjẹ si n jade ṣuruṣuru lẹnu ọkunrin naa.

Ọlọpaa olupẹjọ, A.S.P Raji Akeem, to foju kọndọkitọ ọhun bale-ẹjọ sọ niwaju Onidaajọ Bọla Ọṣunsanmi pe Ọgbẹni Shina ti wọn fi ẹṣẹ yọ eyin rẹ  lo waa fẹjọ sun awọn ọlọpaa agbegbe ọhun, ti wọn fi lọọ fọwọ ofin mu kọndọkitọ naa lẹnu iṣẹ rẹ. O ni iwa ti Azeez hu lodi, o si ta ko ofin iwa ọdaran eyi tipinlẹ Eko n lo.

Loju-ẹsẹ ti wọn ti ka awọn ẹsun ọhun si i leti ni kọndọkitọ ọhun ti sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Bọla Ọṣunsanmi ni ki wọn gba beeli kọndọkitọ naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun Naira ati oniduuro meji ti wọn lorukọ laarin ilu, ọ si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.

 

Leave a Reply