Nitori ogun eeyan ti mọto tẹ pa lẹẹkan naa, awọn araalu fẹhonu han l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade,Akurẹ 

Ọgọọrọ awọn araalu ni wọn jade lati fẹhonu han ta ko iṣẹlẹ ijamba ọkọ to n fẹmi awọn eeyan ṣofo lagbegbe Akoko laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

Ọkọ tirela to ṣokunfa ijamba to ṣẹṣẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lawọn olufẹhonu ọhun kọkọ dana sun, lẹyin eyi ni wọn tun di ọna marosẹ Ọwọ si Ikarẹ Akoko pa, ti wọn ko si fun awọn awakọ akero ati ti aladaani ti wọn rin si asiko naa laaye ati kọja fun ọpọlọpọ wakati.

Oriṣiiriṣii akọle bii ‘Ewu nla ni ijamba ọkọ gbogbo igba jẹ fun wa’, ‘Iku ojiji yii ti pọ ju l’Akungba Akoko’, ‘A fẹ ki Gomina Akeredolu tete waa ran wa lọwọ’ ati beẹ bẹe lọ lawọn ọdọ to n binu naa kọ sara awọn patako ti wọn gbe lọwọ lasiko ti wọn fi ṣe iwọde.

O kere tan, awọn bii ogun la gbọ pe ọkọ ajagbe ọhun tẹ pa ninu ọja Ibaka to wa niluu Akungba lalẹ ọjọ Abamẹta tiṣẹlẹ yii waye.

Lara awọn to ku naa ni awọn ọmọdekunrin meji kan ti ọkọ akẹru naa kọ lu nibi ti wọn ti n ta fufu.

Mọsuari ileewosan ijọba to wa ni Ikarẹ ati Iwarọ Ọka Akoko la gbọ pe wọn ṣi tọju oku awọn to ku naa si lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply