Nitori ẹgunjẹ ogun naira, ẹ wo bawọn ọlọpaa ṣe fi ibọn ba ẹnu mi jẹ – Ọdẹyẹmi

Florence Babaṣọla, Osogbo

‘Mi o le sọrọ daadaa mọ, mi o le gbe itọ (saliva) mi daadaa, ti mo ba rin lọsan-an, ẹjẹ ati itọ maa n jade latẹnu mi.’ Ọkan lara awọn olupẹjọ to fara han niwaju igbimọ to n gbọ ẹsun nipa iwa ibajẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, Ọgbẹni Amos Ọdẹyẹmi lo sọrọ taaanu taaanu beẹ.

Ọkunrin yii ṣalaye fun awọn igbimọ pe lọdun 2003 ni Kọnstebu ọlọpaa kan, Ọlalere George, to ni nọmba 367218 PC yinbọn mọ ọkọ bọọsi toun wọ niluu Okuku, nitori ẹgunjẹ ogun naira (#20), eeyan meje ninu awọn mejidinlogun ti wọn wa ninu ọkọ naa ni wọn si fara pa yanna-yanna.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Oniṣowo ni mi, lọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2003, ni mo wọ mọto bọọsi kan to ni nọmba XC 778 SGB niluu Oṣogbo, mo fẹẹ lọ ra eeso Cashew niluu Ọfa, nipinlẹ Kwara.

“Nigba ti a de oju-ọna Railway Crossing, niluu Okuku, a ba awọn ọlọpaa nibẹ, wọn si da Ibrahim Ọlagoke to jẹ awakọ wa duro, ọkan lara wọn nawọ si awakọ wa lati gba ogun naira ti wọn maa n gba nigba naa, awakọ wa si fun un, lẹyin rẹ lo ni ka maa lọ.

‘’Ṣugbọn bi mọto wa ṣe gbera ni ọlọpaa mi-in, Ọlalere George, fibinu yinbọn si mọto wa, o ro pe awakọ wa ko ti i sanwo to fi fẹẹ maa sa lọ ni. Latẹyin ni ọta-ibọn kan ti wọ ori mi, o si fọn ẹnu mi, ete mi, eyin ati agbọn-isalẹ mi ka, bẹẹ ni ẹjẹ bẹrẹ si i ṣan lara mi.

“Mo ṣubu lulẹ, awọn ọlọpaa yii sa lọ, gbogbo awa ti ọta ibọn yẹn ba wa n jẹrora nilẹ, awọn ti wọn n kọja ni wọn gbe wa lọ sileewosan LAUTECH, niluu Oṣogbo, ko too di pe wọn gbe emi lọ si OAUTHC, n’Ileefẹ, lati yọ ọta ibọn to wa lori mi. Dokita Vincent Ugboko lo ṣaaju awọn onimọ-iṣegun oyinbo to ṣiṣẹ abẹ fun mi.

“Gbogbo nnkan ini mi ni mo ta lati fi tọju ara mi, mi o le sọrọ daadaa mọ, mi o le gbe itọ (saliva) mi daadaa, ti mo ba rin lọsan-an, ẹjẹ ati itọ maa n jade latẹnu mi. Nigba ti mo pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ, miliọnu kan naira pere nile-ẹjọ ni ki awọn ọlọpaa ṣan fun mi, eleyii ti ko ran nnkan kan ninu iṣẹ-abẹ ti mo nilo.

“Ọmọ ọdun mejilelọgọta ni mi bayii, mo niyawo kan, mo si bimọ mẹta, ṣugbọn n ko lagbara iṣẹ mọ bayii. Ohun to buru ju ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣe nnkan kan fun Ọlalere to yinbọn atawọn ti wọn jọ wa nibẹ lọjọ naa, ṣugbọn mo nigbagbọ pe awọn igbimọ yii yoo ṣedajọ ododo lori ipo ti mo wa yii”

Leave a Reply