Nitori ọkada ti wọn gba, awọn ọlọkada kọ lu ẹṣọ oju popo ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Niṣe lọrọ di wahala laarin araalu atawọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo kan lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, nikorita ilu Shao, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara, lori ẹsun pe wọn gba ọkada lọwọ ọlọkada kan ti wọn ni ko de akoto, iyẹn ‘helmet’.

Ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ naa to sọ fun ALAROYE ṣalaye pe ọlọkada ọhun wa lori ọkada rẹ, to n gun un lọ lopopona Olóoru, nibẹ lawọn ẹṣọ alaabo ọhun ti da a duro, ti wọn si gba ọkada lọwọ rẹ, wọn gbe e sinu mọto wọn.

Eyi lo bi ọlọkada atawọn eeyan to wa nibi iṣẹlẹ naa ninu ti wọn fi doju ija kọ awọn ẹṣọ oju popo ọhun, ṣe ni wọn fipa wọ ọkada ọhun jade ninu ọkọ wọn, ti iyẹn si gbe ọkada rẹ sa lọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ naa pada mu ẹni kan, to si ti n ṣẹju peu ni galagala bayii.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Alukoro ẹṣọ ojupopo ni Kwara, Oluṣẹgun Ogungbemide, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, o waa bu ẹnu atẹ lu akọlu tawọn ọlọkada ṣe si awọn oṣiṣẹ wọn yii.

O ni loootọ ni ọlọkada atawọn araalu kan kọ lu awọn oṣiṣẹ oju popo to wa lẹnu isẹ wọn lẹyin ti wọn gba ọkada ọkunrin kan ti iwe rẹ ko pe nigba ti wọn ṣe ayẹwo fun un. O waa ni ajọ yii ko ni i faaye silẹ ki wọn maa kọ lu awọn oṣiṣẹ awọn, o ni iwa buruku gbaa ni ọlọkada ọhun hu, ti ko si jẹ itẹwọgba rara.

Leave a Reply