Nitori oko oloko ti Gabriel lọọ fina si l’Ekiti, adajọ ti ran an lẹwọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Ode Gabriel, ni ile-ẹjọ kan to wa ni Ado-Ekiti, ti ran lẹwọn ọdun meje bayii, lori ẹsun pe o fi ina si oko koko ati obi ni abule Ode-Omu, ni Erio-Ekiti, nijọba ibilẹ Ijero, n’ipinlẹ Ekiti.

Ọmọdekunrin to jẹ akẹkọọ ileewe girama kan to jẹ tijọba nipinle Ekiti ni wọn sọ pe o fina si oko koko nla kan, oko obi ati ọgẹdẹ ati awọn ohun miiran ni akoko ọgbẹlẹ lọdun 2019.

Adajọ ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Lekan Ogunmoye so pe, “Pẹlu ẹri to daju to wa niwaju ile-ẹjọ yii, o fi han gbangba pe loootọ ni adaran naa ṣẹ ẹṣẹ naa.

“Ni gbogbo rẹ, o fi han daju gbangba pe loootọ ni awọn olupejọ wọnyi fi idi ẹjọ wọn mulẹ pẹlu ẹri to daju pe loootọ ni ọmọdekunrin Gabriel yii ṣe ẹṣẹ yii.

“Ile-ẹjọ yii sọ ọkunrin yii sẹwọn ọdun meje pẹlu iṣẹ aṣekara tabi ko san ẹgbẹrun mẹẹẹdogun lori ẹsun kọọkan pẹlu ẹsun oniga marun-  ti wọn fi kan an”

Ninu iwe ẹsun ti wọn fi kan Gabriel yii, wọn ni  o ṣẹ ẹṣẹ naa lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2019, ni abule Ọdẹ-Omu, ni Erio, nigba to tan ina si oko koko nla kan to tun ni ọgẹdẹ ati awọn ohun ọgbin miiran  ninu, to jẹ ti Ọgbẹni Salad Ismaila, Yusuf Wasiu, Jimoh Moshood ati Morufu Popoola.

Ẹsun yii ni ọlọpaa ile-ẹjọ naa, Insipekitọ Daniel Oyewọle sọ pe o lodi sofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ekiti, ti ọdun 2012, to si ni ijiya labep ofin.

Lati fi idi ẹsun naa mulẹ, Insipepkito ọlọpa yii pe ẹlẹrii mẹfa lati waa jẹrii ni ile-ẹjọ naa, to si tun ko aworan oko naa ati iwe ti Gabriel kọ to fi jẹwọ pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa, nigba ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ.

Ṣugbọn ọdaran naa ninu awijare rẹ pẹlu agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Daniel Ajaja rawọ ẹbẹ si Ile-ẹjọ naa lati ṣiju aanu wo onibaraa oun, eyi ti ile-ẹjọ naa kọ lati gba ẹbẹ naa.

Leave a Reply