Nitori oku Fulani ti wọn ri ninu igbo, awọn eeyan n sa kuro niluu l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn olugbe ilu Akoko kan la gbọ pe wọn ti n sa kuro nibugbe wọn nitori ibẹru akọlu awọn Fulani ti wọn le waa gbẹsan iku ọkan lara wọn ti wọn ṣalabaapade oku rẹ ninu igbo l’Ajọwa Akoko.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun, awọn olugbe ilu bii Eriti, Igasi, Ajọwa, Akunnu, Gedegede ati Ikaram Akoko ni wọn ko loju oorun mọ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, latari ahesọ ọrọ ti wọn n gbọ pe awọn Fulani ti n pete ati waa ṣe akọlu si wọn latari ẹni wọn ti wọn pa sinu igbo ọhun.

Ninu alaye ti ọkan ninu awọn araalu ta a forukọ bo lasiiri ṣe fun wa, o ni awọn Fulani kan ti awọn jọ n gbe lo yọ ọ sọ fawọn eeyan pe awọn bororo kan ti n ko ara wọn jọ lati waa ṣakọlu ojiji sí awọn eeyan agbegbe tiṣẹlẹ ọhun ti waye.

O ni awọn majeeti-o-di ọhun fi kun un pe ohun tawọn to fẹẹ waa ṣe akọlu naa n fẹ ni pe ki awọn Fulani to ti moju ilẹ lagbegbe Akoko le ṣatilẹyin fun wọn ki erongba ibi ti wọn n gbero rẹ baa ṣe e ṣe.

O ni lati igba tawọn ti gbọ ọrọ yii lọkan awọn ko ti balẹ mọ, ti ọpọlọpọ awọn ti ko laya si ti n kẹru ati ẹbi wọn sa kuro lawọn ilu mẹfẹẹfa ti wọn lo ṣee ṣe ki wọn foju wina akọlu to n bọ naa.

Ọkan-o-jọkan ipade lo ni awọn ilu n ṣe lọwọ pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante lori bi wọn yoo ṣe daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan to ba jẹ pe loootọ lawọn onisẹẹbi ọhun fẹẹ waa pa itu ọwọ wọn.

Gbogbo akitiyan wa lati ri alaga ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Alagba Ayọdele Akande, ba sọrọ ni ko so eso rere.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Odulami, ta a ba sọrọ ni oun ko ti i gbọ ohun to jọ bẹẹ ni toun.

Ọlọpaa kan to ba wa sọrọ laṣiiri lati ilu Akoko ni loootọ lawọn eeyan ri oku Fulani kan ninu aginjù ibi tó ku si lọsẹ to kọja.

Loju-ẹsẹ ti wọn ti gbọ nipa rẹ lo ni awọn ti debẹ, ti awọn si gbe oku ọhun lọ si mọṣuari.

Leave a Reply