Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ojiṣẹ Ọlọrun kan to filu Iwarọ Akoko ṣebugbe, Pasitọ Friday Okeneji, ti dero ẹwọn bayii o. Adajọ ile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ si agbegbe NEPA, l’Akurẹ, lo ran an lẹwọn lẹyin ti wọn lo jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.
Pasitọ Friday ti wọn lo jẹ olusọaguntan Ijọ Aposteli Kirisiti ((CAC), Ọna Iwa-Mimọ, eyi to wa niluu Iwarọ Akoko ni wọn fẹsun kan pe o lọọ ja ṣọọbu oniṣọọbu lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Keje, ta a wa yii ninu ilu kan naa ti sọọsi rẹ wa.
Awọn kẹmika ti wọn fi n fin oko ti apapọ owo rẹ to ẹgbẹrun lọna aadoje Naira (#130,000) la gbọ pe Pasitọ yii ji ko ninu ṣọọbu oniṣọọbu to fọ
Awọn ẹsun mejeeji, iyẹn ile onile fifọ ati ole jija, ti wọn fi kan olujẹjọ ni agbefọba juwe bii eyi to ta ko iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Loju-ẹsẹ ni Pasitọ Friday ti gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, to si bẹ adajọ kootu ọhun pe ko ṣiju aanu wo oun nitori oun ko deedee huwa naa. Ṣe bi ko ba nidii, obinrin ki i jẹ Kumolu.
Ojiṣẹ Ọlọrun ọhun ni ẹgbẹrun lọna àádọ́jọ Naira (#150,000), lowo ti wọn bu fun oun lati san fun isinku iya oun, eyi ti awọn fẹẹ ṣe ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii. Aitete ri owo ọhun san lo ni o sun oun de idi iṣẹ ole jija, lai mọ pe ọrọ yii yoo pada yiwọ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni ni ko tete lọọ f’ẹwọn ọdun meji jura tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira gẹgẹ bii owo itanran ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, to si jẹbi wọn.
Adajọ waa gba ọkunrin naa nimọran pe ko jawọ ninu iwa ibajẹ, ko si gbiyanju lati lọọ tẹpa mọṣẹ pẹlu adura gbigba ni ibamu pẹlu ilana ti Bibeli fi lelẹ fawọn Kirisitiẹni ninu Majẹmu Tuntun.