Nitori ọkunrin, Jẹmila atọrẹ ẹ dana sun Rabi mọle ololufẹ ẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ahamọ ọlọpaa ni ki wọn fi Jẹmila Ibrahim, ẹni ọdun mọkandinlogun, ati ọrẹ ẹ, Fatimah Mohammed, ẹni ọdun mọkanlelogun si, latari bi wọn ṣe lọọ dana sun ile Ọgbẹni Mohammed Yusuf to jẹ ololufẹ Jẹmila tẹlẹ, ti wọn tun sun Rabi, ọmọge tiyẹn ṣẹṣẹ n fẹ mọle.

Nnkan bii irọlẹ Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, la gbọ pe awọn ọrẹ mejeeji yii gbimọ-pọ, ti wọn sọ ina si ile ọkunrin naa to wa ni Monkey Village, lagbegbe Festac, nipinlẹ Eko, ni wọn ba sa lọ, ṣugbọn ọwọ agbofinro pada tẹ wọn lọjọ Aje, Mọnde yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọbi, ṣalaye pe ololufẹ ni Mohammed ati Jẹmila tẹlẹ, ija lo de laarin wọn lawọn mejeeji fi pinya, wọn ni Mohammed fẹsun kan Jẹmila pe oju ẹ ko gbebikan, lo ba sọ pe oun ko ṣe mọ.

Wọn ni ko ju ọjọ meloo kan lẹyin naa ni ọkunrin naa bẹrẹ si i fẹ Rabi, eyi ko si dun mọ Jẹmila ninu rara, tori agbegbe Festac kan naa yii lawọn mejeeji n gbe.

Wọn ni Jẹmila fẹnu ara ẹ ṣalaye ni teṣan ọlọpaa pe ibinu ohun ti afẹsọna oun ṣe yii lo mu koun pinnu lati gbẹsan lara ẹ, loun ati ọrẹ oun fi lọọ dana sun ile ẹ, ṣugbọn awọn ko mọ pe Rabi n sun ninu ile ọhun lọjọ naa, tori titi pa loun ba ilẹkun.

Wọn lo jọ pe olobo iṣẹlẹ naa ta Mohammed nibi to lọ, lo ba sare wale, ṣugbọn ile rẹ ti n jo lọwọ nigba to fi maa debẹ. Ọpẹlọpẹ awọn araadugbo naa ni wọn kori bọnu ina ọhun lati doola ẹmi Rabi ti wọn sun mọle, ni wọn ba sare gbe e digbadigba lọ sọsibitu aladaani kan to wa nitosi.

Ọsibitu naa ni wọn lo pada dakẹ si lọjọ keji iṣẹlẹ naa.

Atigba yii lawọn ọlọpaa ti n wa Jẹmila ati ọrẹ ẹ, aṣe ile kan lagbegbe Satelite ni wọn lọọ sa pamọ si. Awọn ọlọpaa teṣan Satelite ni wọn tọpinpin wọn tọwọ fi ba wọn nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Odumosu ti ni ki wọn taari wọn si ẹka ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba, fun iwadii. O ni awọn maa ri i pe iya to tọ si awọn afurasi ọdaran naa to wọn lọwọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply