Nitori ọkunrin ti wọn ji gbe, Amọtẹkun, ọlọpaa ati ọdẹ koju awọn ajinigbe l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ikọ State Security Network Agency tawọn eeyan mọ si Amọtẹkun pẹlu awọn ọlọpaa ati ọlọdẹ ti gba ọkunrin kan silẹ lọwọ awọn ajinigbe lẹyin tawọn ọdaran naa ji eeyan meji gbe lọjọ Keresi.

Ọkunrin tori ko yọ naa, Happiness Ajayi, loun ati mọlẹbi ẹ kan to n jẹ Oluwaṣeun Fatile ko sọwọ awọn oniṣẹ laabi ọhun loju ọna Iṣan-Ekiti si Iludun-Ekiti, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lasiko ti wọn n lọ siluu Ẹda Oniyọ toun naa wa l’Ekiti.

Oju ọna yii kan naa lawọ̣n ajinigbe ti ji Komiṣanna feto ọgbin nipinlẹ naa, Fọlọrunṣọ Ọlabọde, gbe, ti wọn si pa kanṣẹlọ to wa mọto ọhun, Ọlatunji Ọmọtọshọ, loṣu kẹrin, odun yii.

ALAROYE gbọ pe ọkọ jiipu Lexus kan ni Happiness ati Oluwaṣeun gbe kawọn eeyan naa too deede yọ si wọn lojiji, bi wọn si ṣe fẹẹ sare dari ọkọ naa pada lawọn mi-in yọ si wọn lati ẹyin ti wọn si da ibọn bolẹ.

Ọkọ kan to wa lẹyin atawọn to wa lagbegbe naa la gbọ pe wọn sare pe ikọ Amọtẹkun tawọn yẹn si ri Oluwaṣeun gba silẹ kawọn ajinigbe too ri Happiness gbe lọ.

Nigba to n sọ bi iṣelẹ naa ṣe waye, adari ikọ Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlaf̣e, sọ pe nigba tawọn ajinigbe naa ti ko awọn meji ọhun ni papa mọra, wọn ṣilẹkun ọkọ, wọn si bẹ sinu igbo, bẹẹ lawọn ajinigbe ọhun le wọn.

O ni nigba ti ikọ Amọtẹkun de tawọn ọdaran naa si ri i pe oju ogun le ni wọn sare gbe Happiness lọ.

O waa ni lati asiko iṣẹlẹ naa lawọn ọmọ ikọ oun ti ya bo igbo naa, ti wọn si n wa ẹni ti wọn gbe yii kiri. Bakan naa lo fọkan awọn araalu balẹ pe ko sewu, nitori ikọ naa n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaabo mi-in lati pese aabo to peye.

Ninu alaye tiẹ, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekiti, sọ pe awọn eeyan to wa lagbegbe iṣẹlẹ naa lo pe awọn ọlọpaa Ọyẹ-Ekiti, ọga ọlọpaa ibẹ gan-an lo si ṣaaju awọn to lọọ koju awọn ajinigbe ọhun.

O sọ ọ di mimọ pe ajọṣepọ ọlọpaa, Amọtẹkun atawọn ọdẹ lo jẹ kawọn ri ẹni kan gba silẹ, awọn si n wa ẹni keji lọwọlọwọ.

Leave a Reply