Nitori olu ile ẹgbẹ APC ti wọn dana sun, awọn mẹta foju bale-ẹjọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn afurasi mẹta ni wọn ti n jẹjọ ni kootu Majisireeti Oke-Ẹda, to wa l’Akurẹ, lori bi wọn ṣe jo olu ile ẹgbẹ oṣelu APC  lasiko rogbodiyan to bẹ silẹ nigba ti wọn n ṣe iwọde SARS.

Okebiyi Oluwatosin ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Ẹkundayọ Oluwaṣeun, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati Ibrahim Jubril, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ni wọn ko wa sile-ẹjọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lori ẹsun igbimọ-pọ huwa to lodi sofin, biba nnkan oni nnkan jẹ, ole jija ati dida igboro ru.

Awọn olujẹjọ naa pẹlu awọn afurasi kan tawọn ọlọpaa ṣi n wa ni wọn fẹsun kan pe wọn dana sun olu ile ẹgbẹ naa, ti wọn si tun ji ọpọlọpọ ẹru ko ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ kokanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Wọn lawọn afurasi ọhun ti huwa to lodi si abala Okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516), Okoolenirinwo o le mẹta (443), ikẹrindinlọgọrin (76) ati ọrinlelọọọdunrun-un o le mẹta (383) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo tọdun 2006.

Suleiman Abdulateef to jẹ ọlọpaa agbefọba bẹbẹ ki wọn ṣi fi awọn gende mẹtẹẹta ọhun pamọ sọgba ẹwọn na titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

Awọn agbẹjọro wọn ta ko aba yii, wọn ni kile-ẹjọ fun awọn laaye diẹ ki awọn fi raaye da esi ẹbẹ agbefọba pada.

Nigba to n gbe ìpinnu rẹ kalẹ, Adajọ T. A. A. Oyedele ni oun fọwọ si ibeere awọn agbẹjọro naa, o fun wọn laaye titi dọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, ki wọn fi ṣe bẹẹ.

Leave a Reply