Jọkẹ Amọri
Lati bu ọla fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji Aje Ogungunnisọ 1, to darapọ mọ awọn baba nla rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, Babalọja ilu Ibadan, Alaaji Yẹkini Abass Ọladapọ ti paṣẹ pe ki gbogbo ọja to wa niluu Ibadan wa ni titi pa. Ko gbọdọ si tita ati rira kaakiri gbogbo ọja to wa niluu naa.
Ọladapọ sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fun awọn oniroyin lọjọ Aiku lori ipapoda ọba naa. Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe ‘lorukọ gbogbo awọn oniṣowo niluu Ibadan, Babalọja jẹnera, kẹdun pẹlu awọn ọmọ bibi ilu Ibadan lọkunrin ati lobinrin, Gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ idari Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, awọn agba oye Ibadan, awọn igbimọ apaṣẹ Olubadan ati Olori Rashedat Adetunji lori ipapoda Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kin-in-ni.’
O ni ifọwọsowọpọ kabiyesi pẹlu awọn ọlọja mu ki awọn ọlọja niluu Ibadan ṣe aṣeyọri, ti awọn eeyan si n ba awọn dowo pọ daadaa.
Abass ṣalaye pe lẹyin ipade pajawiri awọn adari awọn ọlọja naa tawọn ṣe lọjọ Aiku lawọn fẹnuko pe ki wọn pa ọja jẹ nitori aikanju ọba naa.
O waa gbadura pe ki ẹyin Ọba Ọlatunji daa.