Nitori ọmọ ẹyin ọkọ ti wọn lawọn TRACE lo pa a, ijọba bẹrẹ iwadii l’ Ogun  

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari rogbodiyan to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, l’Abẹokuta, nibi ti awọn awakọ tirela ti ba ọpọlọpọ nnkan jẹ lọfiisi ajọ TRACE nitori ọmọ ẹyin ọkọ kan ti wọn ni ọwọ ajọ yii ni iku rẹ ti wa, ijọba ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori ẹsun naa lẹsẹkẹsẹ, ki wọn si pe awọn oṣiṣẹ TRACE ti ọrọ naa kan fun ifọrọwalẹnuwo.

Ọfiisi Kọmiṣanna fun igbokegbodo ọkọ, Onimọ-ẹrọ Gbenga Dairo, ni atẹjade ti bọ sita l’Ọjọruu, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, pe bijọba ṣe ba awọn ẹbi ọmọ ẹyin ọkọ to ku naa daro ni wọn tun ṣetan lati tọpinpin ohun to fa a ti wahala naa fi ṣẹlẹ, to bẹẹ ti ẹmi gende fi lọ si i.

Eyi ni wọn ṣe fa iṣẹ naa le Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwo lati bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, wọn ni ki wọn jẹ ko di mimọ boya TRACE lo jẹbi tabi awọn awakọ tirela.

Ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ajọ TRACE sọ pe awakọ tirela kan ru ofin Korona, nigba to rin lasiko tijọba fofin de irin-ajo.  Ibi kan ti wọn n pe ni Water Junction, nitosi Ṣiun, ni tirela naa de ti awọn TRACE fi da a duro gẹgẹ bi Babatunde Akinbiyi to jẹ alukoro wọn ṣe ṣalaye.

O ni awọn eeyan oun da awakọ naa duro, wọn ni ki oṣiṣẹ TRACE kan mu un lọ sibi ti wọn n ko awọn ọkọ to ba lufin si, ṣugbọn niṣe ni dẹrẹba naa dori kọ ọna Ṣagamu, lo ba n sa lọ. Nibi to ti n sa lọ naa ni ọmọ ẹyin ọkọ rẹ ti ja bọ, ti mọto mi-in tiyẹn naa lufin irinna tẹ ẹ mọlẹ.

Iku ọmọ ẹyin ọkọ yii lawọn onitirela ti wọn n pe ni ‘Truck Owners Association of Nigeria’ (TOAN) waa gbẹsan ẹ lọsan-an ọjọ naa ti wọn fi ya bo ẹka ti wọn n ko awọn ọkọ ti TRACE ba mu, ti wọn si tun ya bo ọfiisi ajọ naa n’Ibara, ti wọn ba awọn mọto, awọn ẹrọ to n lo ina loriṣiiriṣii, geeti abawọle ọfiisi TRACE atawọn nnkan mi-in jẹ. Koda, wọn ni wọn tun wọ ẹka ibi ti wọn n kowo si ninu ọgba naa, wọn si ko owo wọn lọ.

Iṣẹlẹ yii ni ijọba ipinlẹ Ogun koro oju si, ti wọn si ni afi kawọn mọ ẹni to jẹbi ọrọ to mu ẹmi ọmọ ẹyin ọkọ lọ yii, to fi di pe awọn onitirela fẹhonu han to bẹẹ.

Leave a Reply