Nitori ọmọọṣẹ ẹ to yan sipo kọmiṣanna ajọ INEC, awọn eeyan n binu si Buhari

Lati bii ọjọ meloo kan lorilẹ-ede yii, o jọ pe ojumọ kan, wahala kan, ni bayii fun ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.
Ẹgbẹ ajafẹtọọ bii aadọrin ni wọn ti fẹhonu han bayii pe awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ko gbọdọ fọwọ si bi Buhari ṣe fẹẹ yan obinrin kan to jẹ ọmọọṣẹ rẹ, Lauretta Onoche, sipo kọmiṣanna fun ajọ INEC nipinlẹ Delta.
Onoche ti wọn n sọ yii, oluranlowo Buhari ni, nipa awọn iroyin ti wọn n gbe sori ayelujara.
Yinka Odumakin, ọmọ ẹgbẹ Afẹnifere, naa ti sọrọ lórúkọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba yìí, ohun tawọn naa si sọ ní pe igbesẹ ọhun ko dara to, ati pe bíi ẹni fẹẹ doju Naijiria dele ni.
Bakan naa ni Odumakin sọ pe, ti obinrin yẹn ba fi di kọmiṣanna, a jẹ pe ọna ti ajọ INEC yoo fi ku patapata niyẹn, ti eto ijọba dẹmokiresi paapaa le doju de ni Naijiria.
Ẹgbẹ PDP naa ti sọrọ. Alukoro ẹgbẹ ọhun, Kọla Ọlọgbọndiyan, ni ọrọ Buhari ko ṣee tẹle, ati pe igbesẹ ẹ yìí, o fẹẹ fí ba nnkan jẹ ni Naijiria ni. Bakan naa lo jọ pe ko ní erongba rere fún eto idibo rere.
Ohun tawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ n sọ bayii ni pe ki Buhari fa iwe obinrin naa ya, ko ya tete fẹlomi-in ranṣẹ.

Leave a Reply