Nitori Ọọni Ile-Ifẹ, Fani Kayọde sọko ọrọ si Tinubu

Minisita to n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu nilẹ wa tẹlẹ to tun jẹ ọmọ bibi ilu Ileefẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, ti sọko ọrọ si gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lori bo ṣe jokoo nigba to n ki Ọọni Ileefẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, nibi ayẹyẹ igbade Ọba Gbọlahan Lawal to je Oniru ti ilẹ Iru, nipinlẹ Eko.

Ọkunrin naa ko le pa ibinu rẹ mọra lori ọrọ yii, niṣe lo kọ ọ sori ikanni ayelujara rẹ bayii pe ‘‘Pe Aṣiwaju Bourdillon kọ lati dide duro ki Ọọni Ileefẹ jẹ ọrọ to loyun sinu. Ki i ṣe pe o jẹ arifin fun awọn ọmọ bibi Ileefẹ ati gbogbo ọmọ Yoruba nikan, o jẹ iwa afojudi nla.

Ṣe aṣaaju ilẹ Hausa kan le maa ki ọba adugbo rẹ lorii ijokoo?’’

Bẹ o ba gbagbe, lati ọsẹ to kọja ti aworan ayẹyẹ igbade ọba oniru naa ti gba ori ẹrọ ayelujara, nibi ti Sẹnetọ Bọla Tinubu ti jokoo lasiko to n ki Ọọni, ti awọn eeyan yooku si dide duro, ni awọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu iwa afojudi ti wọn ni Tinubu hu si ọba nla pataki nilẹ Yoruba yii.

Bawọn kan ṣe n sọ pe igberaga oloṣelu yii pọ lawọn mi-in n sọ pe ko si ohun to na ọkunrin naa to ba dide duro ki Ọọni nitori ki i ṣe ọba naa lo n bọwọ fun bi ko ṣe gbogbo ọmọ Yoruba to gbe ọba yii de ori ipo.

Ṣugbọn awọn kan ti n gbija ọkunrin oloṣelu naa, wọn ni ko si ohun to buru ninu bo ṣe jokoo, pe iyẹn ko sọ pe ko bọwọ fun Ọba Ogunwusi. Ṣugbọn awọn to naka abuku si Bọla Tinubu, ti wọn si ni ko fi iwa aṣaaju rere ati apẹẹrẹ rere lelẹ lo pọ ju lọ.

Lasiko ayẹyẹ naa, eto ti n lọ lọwọ ki Ọọni too wọle. Bi kabiyesi ṣe wọle ni ọpọ awọn to wa lori ijokoo ọlọla n dide duro lati ki i. Ijokoo Tinubu ni ọba naa yoo kọkọ kan ko too kọja lọ sori ijokoo ti wọn pese fun un, eyi lo fi lo anfaani yii lati ki Aṣiwaju, ṣugbọn dipo ki ọkunrin naa dide nilẹ lati yẹ ẹ si, ori ijokoo lo ti n ki Ọba Ogunwusi.

Yatọ si Fani Kayọde, ọpọlọpọ ọmọ Yoruba ni inu wọn ko dun si eyi, wọn ni iwa arifin ati afojudi ni Tinubu hu eyi ti awọn araata le maa wo to le mu ki wọn ma ni ibọwọ to to fun ọba ilẹ Yoruba naa. Awọn kan ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to ju Tinubu lọ ni gbogbo ọna paapaa ki i duro ki aọn ọba ile Yoruba.

2 thoughts on “Nitori Ọọni Ile-Ifẹ, Fani Kayọde sọko ọrọ si Tinubu

  1. Oro Asiwaju ilu Eko ka fi senu ka dake ni o. Iwa igberaga to hu si oba Okunade Sijuwade ti ohun ati awon alabuku bi tie ko se yoju sibi isinku oba naa ni ye. Ojo nbo ti oni kaluku yo gba ere ohun to gbele aye se.
    Se Tinubu le lo si sokoto tabi Kano ki o ma dide ki emir ibe? Won ko bi da tobe. Se to ba de ipo aare se bi yo ti ma fi awon oba wa ati asa Yoruba wole ni yi? Eniti o ba moo ki won kilo fun ko ma see te aso agba mole. Oloselu nigba ati akoko lori oye sugbon ipo oba titi ti olojo ma fi de ni. Aare alafojudi awa o fe o.

Leave a Reply