Nitori orin ‘Oniduuro Mi’, Iyabọ Ojo sọrọ buruku sawọn oṣere ẹgbẹ ẹ

Faith Adebọla

 Ilu-mọ-ọn-ka oṣere tiata ilẹ wa nni, Iyabọ Ojo, ti sọko ọrọ sawọn oṣere ẹlẹgbẹ ẹ nilẹ Yoruba, o ni alabosi ni wọn, ẹjọ ti ko kan wọn ni wọn n yọjuran si, eyi to yẹ ki wọn da si ni wọn n dakẹ lori ẹ.

Ninu fidio kan to fi sori atẹ ayelujara instagiraamu rẹ, nnkan bii iṣẹju mẹẹẹdogun lobinrin naa fi sọrọ loriṣiiriṣii lori ẹdun ọkan rẹ, o ni o ya oun lẹnu bawọn oṣere tiata ṣe n da si awuyewuye to ṣẹlẹ lori orin “Oniduuro Mi” ti Adeyinka Alaṣeyọri kọ, eyi ti wọn ni Tọpẹ Alabi fẹnu abuku kan, ṣugbọn nigba ti ọrọ Baba Ijẹṣa, iyẹn Ọlanrewaju Omiyinka ṣẹlẹ, ti wọn lọkunrin naa fipa ba ọmọde kan laṣepọ, ọpọ awọn ti wọn n sọrọ lasiko yii ni kẹkẹ pa mọ atioro wọn lẹnu nigba naa. Oṣere yii ni oju aye ati iwa abosi ni ohun ti wọn ṣe.

Bayii ni Iyabọ ṣe sọrọ naa:

Awọn oṣere ilẹ Yoruba ẹlẹgbẹ mi ni mo fẹẹ ta si o, ṣe awọn oṣere yii sun tẹlẹ ni, tori nigba ti ọkan ninu yin ki ọmọ fọtin yiasi (14 years) mọlẹ, to fipa ba a sun, to molẹẹsi ẹ, niṣe ni gbogbo yin sa lọ, a o ri yin o, ṣugbọn eyi ti ko kan yin nisinyii lẹ n da si. Ẹ ni Tọpẹ Alabi sọ pe orin ‘Oniduuro Mi’ o daa, ṣe o sọ fun yin pe Alaṣeyọri to kọrin loun n ba wi, abi Alaṣeyọri gan-an lo ni orin ọhun latilẹ ni. To ba tiẹ waa jẹ Alaṣeyọri lo ni orin naa, ewo lo kan yin nibẹ, tori eyi to kan yin gangan, ẹ o da si i, ẹ mu ohun yin lọ, ẹ o sọrọ, ẹ o beere nipa ẹ, ṣugbọn gbogbo yin bẹrẹ si i poosi fidio sori ayelujara, meloo ninu yin lo lọọ wo Princess nigba tọrọ Baba Ijẹṣa ṣẹlẹ, abi kẹ ẹ beere ọmọ tọrọ ṣẹlẹ si nigba yẹn.

Kaka kẹ ẹ sọrọ sibi tọrọ wa, iwikuwii lẹ n wi, niṣe lẹ n sọ ‘boya bẹẹ ni, boya bẹẹ kọ, o fa a, ko fa a, ọmọ tuẹti fọọ (24) ni, ọmọ sẹbinti-tuu (72)’, ṣugbọn nigba ti eleyii ṣẹlẹ, gbogbo yin le n gbe fidio ‘Oniduuro mi o ṣeun o’ kiri, meloo ninu yin gan-an lo ti pe ọmọ naa si pati tabi to nawo fun un ri ninu yin, ti gbogbo yin waa n sọ pe ‘we stand with you’, meloo ninu yin lo duro pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn fipa ba lo pọ. Mo sọ ọ nigba yẹn pe ẹ o ki i ṣeeyan gidi lagbo oṣere wa, mo si sọ ọ pe to ba jẹ ara ita lo ni wọn fẹsun kan ni, ọpọ yin lẹ ti maa maa pariwo, ẹ maa fẹẹ ṣewọde, ṣugbọn nitori o jẹ Baba Ijẹṣa, ẹ o rẹnu sọrọ, ṣe o tan, abi ko pari. Ẹ o ki i ṣeeyan daadaa, ootọ ọrọ ko ni ka ma sọ oun, ẹ le ma laiki mi, ṣugbọn ma a maa sọ ọ. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ dakẹ nigba ti Baba Ijẹṣa yẹn ni mo n ba wi o.

Alaṣeyọri o ṣẹ mi o, oun lo waa kọrin lọjọ wake keeping iya mi, mi o si fara mọ ohun ti Tọpẹ Alabi sọ yẹn, ṣugbọn abosi ẹyin onitiata ni mo lodi si, ẹ lọọ ṣọra yin o, ẹ ṣọra yin gan-an ni. Mo n rẹkẹ yin, mo si ti sọ pe gbogbo igba tẹ ẹ ba ti n da si ohun ti ko kan yin ni ma a maa jade, ma a maa fun un yin lọrọ, tori alabosi ni yin.”

Ṣe isọrọ nigbesi, ọpọ eeyan lori ikanni Iyabọ Ojo lo ti n fesi si ọrọ to sọ yii, ọpọ lo si n sọ pe ọrọ tobinrin naa sọ kọja ẹnu ẹ, wọn ni oun gan-an lolori alabosi, wọn ni ija onija loun naa n bẹ si.

Ṣugbọn a ko ti i mọ bi awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ ṣe maa dahun si oko ọrọ ati abuku to sọ si wọn yii, esi ti wọn yoo fun un lẹnikan o ti i le sọ.

Leave a Reply

//betzapdoson.com/4/4998019
%d bloggers like this: