Nitori ọrọ aabo, Gomina Dapọ Abiọdun ati Ṣeyi Makinde fẹẹ ṣeto awọn agbofinro ẹnuubode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu bi ijinigbe, ole jija, ipaniyan, wahala awọn Fulani darandaran lojumọmọ atawọn mi-in ṣe n gbilẹ si i, ijọba Ogun ati Ọyọ ti bẹrẹ igbesẹ lati gbe awọn ẹṣọ alaabo ẹnuubode kalẹ, lawọn ibi ti awọn ilu mejeeji yii ti pade.

Eyi naa lo fa a ti Gomina ipinlẹ Ogun, Gomina Dapọ Abiọdun, ṣe gbalejo Gomina Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde, l’Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, l’Ọjọruu, ọjọ keji, oṣu keji yii. Nibẹ ni wọn ti jọ fẹnuko lati gbe awọn ẹṣọ alaabo yii kalẹ laipẹ rara.

Yatọ si agbekalẹ awọn ẹṣọ alaabo, awọn gomina yii tun sọ pe awọn yoo fi kamẹra ti yoo maa ka ohun to ba n ṣẹlẹ sawọn oju ọna marosẹ tawọn oniṣẹẹbi ti maa n ṣọṣẹ, atawọn ọna to so ipinlẹ Ogun mọ Ọyọ.

Bakan naa ni wọn pe fun ajọṣẹpọ awọn agbofinro lawọn ilu mejeeji yii, paapaa awọn ti wọn ki i ṣe ọlọpaa, ṣugbọn ti ofin fun laaye lati daabo bo adugbo wọn.

Nigba to n ka apa ibi kan ninu iwe ajọṣepọ toun ati Gomina Abiọdun jọ buwọ lu yii, Gomina Ṣeyi Makinde sọ ọ di mimọ pe lati awọn ẹka agbofinro nipinlẹ mejeeji ni wọn yoo ti yọ awọn ẹṣọ alaabo ẹnu ibode yii, bẹẹ ni ajọṣepọ bii ọmọ iya kan naa ni yoo si wa laarin wọn.

Awọn nnkan mi-in ti wọn tun fẹnu ko si ni pe ipinlẹ Ogun ati Ọyọ yoo jọ maa fi iriri kọ ara wọn nipa iṣẹlẹ to ba n  ṣẹlẹ nipa aabo. Wọn yoo jọ maa kọ ara wọn lọgbọn lori ọna ti aabo tun lefi nipọn si i.

Wọn fi kun un pe ibi ti aabo ba wa ni ọrọ aje ti n ṣe deede, nibẹ nijọba paapaa ti le ni alaafia, eyi lo fa a ti igbesẹ yii fi ṣe pataki, ti yoo si gbera sọ kia.

Ṣaaju ni Gomina Dapọ Abiọdun ti sọ iriri ẹ nipa awọn ọmọ Yahoo atawọn oniwa ibajẹ mi-in, o ni lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin toun ti gbe OP-MESA kalẹ lati kapa wọn ni wọn ti n leri asan soun.

Gomina naa ni kinni kan ti oromọdiẹ le fi aṣa ṣe ko si, ago toun ni yoo de adiẹ awọn oniṣẹẹbi yii gbẹyin, ti wọn yoo kuro nipinlẹ Ogun patapata.

 

Leave a Reply