Nitori ọrọ ayẹwo ẹjẹ ọmọ Flakky Ididowo, ile-ẹjọ n wa baba ọmọ rẹ

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ile-ẹjọ Majisireeti Eko to n gbọ ẹsun ‘ta lo lọmọ’ to n waye laarin Ronkẹ Odusanya, oṣere tiata tawọn eeyan mọ si Flakky Ididowo, ati ọkọ ẹ tẹlẹ, Saheed Ọlanrewaju (Jago), to loun bimọ naa fun, ti kede ọkunrin naa bii ẹni tijọba n wa bayii (Wanted).

Ṣe o tojọ mẹta kan ti tirela ti gba aarin Flakky ati ọkunrin pupa to loun bimọ obinrin fun, ti wọn ko fẹra wọn mọ yii.

Ọmọ ti wọn sọ ni Fareedah Oluwafifẹhanmi naa ni Saheed loun kọ ni baba ẹ, to ni oun ko le gba ọmọ ọlọmọ koun maa pe e ni toun, lọrọ ba di ti kootu.

Bo tilẹ jẹ pe Flakky taku pe Saheed ni baba ọmọ oun, ile-ẹjọ paṣẹ nigba naa pe ẹnu lasan ko le ṣe e, afi ki wọn lọọ ṣayẹwo ẹjẹ lati mọ baba ti oṣere yii bimọ fun, paapaa bo ṣe jẹ pe ohun ti Saheed funra ẹ beere fun ni ayẹwo naa.

Kootu paṣẹ nigba naa pe Jago to fẹẹ ri idi okodoro ọrọ ni ko sanwo ayẹwo ẹjẹ ti wọn n pe ni DNA, eyi ti wọn yoo fi mọ Baba Fifẹ gan-an.

Ṣugbọn lati ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2021, ti kootu naa ti paṣẹ yii,Ọgbẹni Ọlanrewaju ti wọn ni ọmọ jayeyaye ni niko sanwo ayẹwo, wọn tilẹ ni o sa lọ patapata ni, nitori ko sẹni to gburoo rẹ, bẹẹ ni ayẹwo naa wa bẹẹ ti ko ṣe e.

Nigba ti kootu reti abọ ayẹwo titi ti wọn ko gburoo ọkọ Ronkẹ, wọn tun ranṣẹ pe e lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii, pe kawọn tun jokoo lori ẹjọ naa lẹẹkan si i, ṣugbọn Saheed ko tun wa, ẹnikẹni ko ri i titi ti kootu fi pari iṣẹ lọjọ naa, bẹẹ ni ko yọju lẹyin ọjọ igbẹjọ yii lati ṣalaye idi ti ko fi wa.

Bo ṣe waa di pe kootu pari iṣẹ fọdun 2021 ti wọn ko tun gburoo Jago lọjọ ti wọn pari iṣẹ ọdun yii ni wọn fi ikede sita pe Saheed ti Flakky loun bimọ fun ti di ẹni tijọba n wa.

Wọn ni wantẹẹdi ni maanu naa bayii, nitori funra rẹ lo beere fun DNA, ti kootu fun lanfaani ẹ, to waa sa lọ lai pari ohun to bẹrẹ, eyi si lodi labẹ ofin.

Ni bayii ṣa, wọn n wa Saheed lori ẹsun ta lo lọmọ ti Flakky loun bi fun un.

Leave a Reply