Nitori ọrọ buruku to sọ si Baba Adeboye, awọn pasitọ n binu si Buhari

Wẹrẹ bayii lọrọ ọhun bẹrẹ, nigba ti Baba Adeboye, olori ijọ Ridiimu, gba Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, nimọran lori atunto Naijiria, ṣugbọn tawọn ọmọ ẹyin ẹ kọlu baba naa, ti wọn si pe e ni ọta orilẹ-ede yii.

Ọrọ ti wọn sọ yii lo bi Olori ijọ kan ti wọn n pe ni DayStar Christian Centre l’Ekoo, Sam Adeyẹmi, ninu. Ọkan lara awọn pasitọ ti wọn lorukọ nilẹ yii ni ni ọkunrin yii, o si ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ buruku tawọn ọmọ ẹyin Buhari sọ si Baba Adeboye, bẹẹ lo sọ pe ki i ṣe ẹṣẹ rara ti eniyan ba sọ ero ọkan ẹ nipa orilẹ-ede ẹ fun ijọba.

Ori ẹrọ ayelujara abẹyẹfo (twitter), ni Adeyẹmi gba ti sọ pe nigba wo lo di ki wọn maa dunkooko mọ araalu nitori ti wọn sọ ero ọkan wọn sita. O ni ẹtọ kaluku ni lati sọ ohun to yẹ fun ijọba nipa atunto orilẹ-ede yii. Ati pe niṣe ni olori gidi maa n tẹti lati gbọ ohun tawọn eeyan ẹ ba sọ, ki i ṣe idunkooko tabi ki wọn maa halẹ kiri.

Bakan naa ni awọn iranṣẹ Ọlọrun mi-in, to fi mọ awọm ọmọ orileede yii ti n sọ pe ọrọ ti Garba sọ lorukọ Aarẹ ku diẹ kaato. Wọn ni lara ojuṣe iranṣẹ Ọlọrun ni lati tọ awọn aṣaaju wa sọna, ojuṣe yii ko yọ awọn ọmọ Naijiria paapaa silẹ, nitori awọn ni wọn yan wọn sipo, wọn si gbọdọ maa gbe amọran tabi akiyesi ti wọn ba fun wọn wo.

Lana-an ni Ọgbẹni Garba Shehu, oluranlọwọ fun Aarẹ Muhammed Buhari lori eto iroyin bọ sita, ohun to si sọ ni pe ti a ba ri ẹnikan to ba n sọ nipa atunto Naijiria lasiko yii, ọta orilẹ-ede yii niru wọn. O sọ pe ko si ọrọ atunto kankan ninu iṣẹ to wa niwaju Muhammed Buhari, bẹẹ ni ko ni i ṣe e, wọn o baa pariwo ju bẹẹ lọ.

Ohun to fa ibinu awọn eeyan ko ju pe, Baba Adeboye, olori ijọ Ridiimu, ṣẹṣẹ gba Muhammed Buhari niyanju ni, bi awọn eeyan si ṣe n ka iroyin ọhun lọwọ, ko pẹẹ ni Garba Shehu gbe tiẹ naa jade, ohun tawọn eeyan si n sọ ni pe dajudaju, Adeboye, Olori ijọ Ridiimu gan-an lawọn ọmọ Buhari n pe ni ọta ilu, wọn si mọ-ọn-mọ kan an labuku lori ọrọ to sọ ni.

2 thoughts on “Nitori ọrọ buruku to sọ si Baba Adeboye, awọn pasitọ n binu si Buhari

  1. E yi ko ge iroyin gi di ri afi iroyin ti ko ni ese ni ile ti be iroyin to ole da iluru ni ti yin, laipe ko ni si e ni ti yo ma ka iwe iroyin yin mo ti e ko ba yi iwa yin pa da

Leave a Reply