Nitori ọrọ ijaabu, ẹgbẹ Musulumi ni kijọba yi orukọ awọn ileewe kan pada ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Agbarijọ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Musulumi nipinlẹ Kwara ti rọ ijọba Gomina Abdulrazaq lati yi orukọ awọn ileewe girama to jẹ tijọba kan pada nipinlẹ naa, ki alaafia le jọba lori ọrọ ijaabu to n da wahala silẹ.
Ninu iwe kan ti wọn kọ si gomina ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ti alaga ẹgbẹ naa, Alaaji Ishaq AbdulKareem ati akọwe ẹgbẹ, Ọjọgbọn AbdulKadir Ibrahim Abikan, buwọ lu to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ti darukọ igbesẹ mẹfa ti gomina le gbe ki opin le de ba rogbodiyan to n waye lori ọrọ ijaabu awọn ọmọbinrin lawọn ileewe ijọba nipinlẹ naa.
Akọkọ igbesẹ ti wọn sọ pe ki gomina gbe ni yiyi orukọ awọn ileewe ijọba kan to jẹ pe Musulumi ati Krisitiẹni ni wọn dijọ ni wọn pada nipa fifi orukọ ijọba kun un, bii Ansarul Islam Government Secondary School, Ilọrin, Bishop Smith Memorial Government College, Ilorin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ yii sọ pe ki ijọba san owo gba ma binu fun mọlẹbi Oloogbe Habeeb Idris, ti wọn pa ni ọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun 2022, nibi rogbodiyan ọrọ ijaabu to waye nileewe Baptist High School, Ijagbo, nijọba ibilẹ Oyun, nipinlẹ naa.

Wọn ijọba gbọdọ kọ mọṣalaasi titun fun awọn akẹkọọ ati olukọ Musulumi nileewe girama Bishop Smith Memorial College, Ilọrin, lati fi rọpo eyi tawọn tọọgi ẹgbẹ CAN nipinlẹ Kwara wo.

Wọn fi kun un pe ijọba gbọdọ yan kọmiṣanna lẹka eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan miiran, ki wọn si gbe akọwe to wa ni ẹka yii lọ si ileeṣẹ miiran.

Ninu iwe naa ni wọn ti ṣalaye fun ijọba pe wọn gbọdọ fun gbogbo ẹlẹsin ni ominira lati gbadura ni ilana ẹsin Musulumi ati Krisitiẹni lọtọọtọ nigba ti wọn ba n to lori ila nileewe wọn (school assembly), ti wọn o si gbọdọ gbe alufaa tabi pasitọ kankan wa lati ita lati ṣe iwaasu.

Ni igunlẹ iwe naa, ẹgbẹ naa sọ pe ijọba gbọdọ maa gbe awọn ọga ileewe lọ si ibomiiran nibaamu pẹlu bi wọn ṣe kunju oṣuwọn si, ati nibaamu pẹlu ofin ati ilana ẹgbẹ olukọ nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply