Nitori ọrọ ilẹ, awọn ajagungbalẹ lu kabiyesi de ọsibitu l’Ọbafẹmi-Owode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ilu iṣẹmbaye ni Agbamaya,nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun. Afi bi ọrọ ilẹ ṣe di wahala laipẹ yii, ti awọn ajagungbalẹ ya wọlu, ti wọn si ni wọn lu Kabiyesi, Ọba Ismail Ṣokunbi (Olu Agbamaya), pẹlu awọn oloye meji, Oluṣọla Makinde ati Moninuade Ọlọjẹde, to bẹẹ to jẹ ileewosan ni wọn balẹ si.

Lasan kọ lọrọ naa di ohun to kan kabiyesi gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, Bashiru Salaudeen lo ni oun loun ni gbogbo ilẹ Agbamaya, ati pe baalẹ ibẹ loun. Eeka ilẹ aadọta din lẹgbẹrun kan (950 acres) ti ọkunrin naa ni toun ni lo fa wahala, to fi di ohun to kan kabiyesi atawọn oloye yii.

Wọn tilẹ fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa ni kọmandi ọlọpaa to wa ni Eleweeran l’Abẹokuta leti, ṣugbọn eyi ko mu nnkan kan jade gẹgẹ bi kabiyesi atawọn tọrọ kan ṣe wi. Ohun to si fa a ni ti ọlọpaa obinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni DSP Toyin Ọmọṣebi, ẹni ti wọn ni agbara ọfiisi ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lo n lo, nitori ẹka ‘Special Tactical Squard’(STS) lo wa.

Wọn ni Bashiru lo n ṣiṣẹ fun, oun naa lo si gbe awọn ajagungbalẹ leyin, ti wọn fi ṣe ọba alaye leṣe.

ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lati le ba Toyin ti wọn fẹsun kan yii sọrọ, nitori ẹka Ayetoro/Itele, nipinlẹ Ogun, ni wọn lo n dari. Ṣugbọn Oyeyẹmi sọ pe Toyin ko si nipinlẹ Ogun, o ni Abuja ni ọlọpaa naa wa, labala ọfiisi ọga agba, ọwọ kọmandi ipinlẹ Ogun ko si nibẹ rara.

Nigba ti ọrọ naa ko fẹẹ lojutuu mọ ni awọn eekan ti ọrọ naa kan kọwe ifisun si ọga ọlọpaa patapata, IGP Mohammed Adamu, pe ki wọn ba awọn gba ẹjọ naa kuro lọwọ Toyin Ọmọṣebi, ki wọn si rin in lọna ofin pẹlu Bashiru naa, nitori ifiyajẹni to kan ọba alade atawọn ijoye ko mọ bẹẹ, abuku gbogbo ilu ni.

Leave a Reply