Nitori ọrọ SARS, awọn ọlọpaa ti gbọngan Africa Shrine pa l’Ekoo

Jide Alabi

Gbagbaagba ni awọn ọlopaa duro si ẹnu ọna gbọngan igbafẹ African Shrine, to jẹ ti Oloogbe Fẹla Anikulapo, to wa ni Ikẹja, nipinlẹ Eko, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni wole sinu gbọngan naa.

Eyi ko sẹyin eto kan ti Ṣeun Kuti, ọkan ninu awọn ọmọ Fẹla Anikulapo, fẹẹ ṣe nibẹ, iyẹn agbeyẹwo ati  aṣeyọri bi iwọde ta ko SARS, eyi to waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii, ṣe lọ si.

Wọn ni oju tawọn fi wo eto ọhun ni pe o le da wahala silẹ laarin ilu, paapaa niru asiko ti ipinlẹ Eko n wa bi alaafia ati ifayabalẹ yoo ṣe pada siluu.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, gan-an lo fi eto ọhun si, kawọn ọlọpaa too sọ pe awọn yoo sọ ọ di wahala mọ ọn lọwọ.

Ileeṣe ọlọpaa ti kọ lẹta sawọn mọlẹbi Kuti to ni gb̀ọngan African Shrine pe awọn yoo ti ibẹ pa, nitori  ijọba ko fọwọ si iru eto bẹẹ lasiko yii, nitori o ṣee ṣe ko ṣakoba fun awọn eto daadaa ti ijọba ti ni lọkan fun araalu.

Ohun tawọn ̀ọlọpaa wi niyẹn o, ṣugbọn Ṣeun Kuti toun naa jẹ olorin nla laarin awọn ọmọ Oloogbe Fẹla Anikulapo ti sọ pe o ti di dandan ki eto ọhun waye, bo tilẹ jẹ pe awọn ko ni i ṣe e mọ ni gbọngan African Shrine.

O ni, “Mo ti pinnu bayii lati tẹle aṣẹ awọn ẹbi mi pe a ko gbọdọ ṣe e mọ ni gbọngan tiwa, ṣugbọn mo ṣetan lati dara pọ mọ awọn ẹlẹgbẹ mi yooku lori bi a oo ṣe ṣe ipade wa, mi o lero pe o yẹ ki iyẹn jẹ iṣoro.

“Ijọba ko ṣẹṣẹ maa di wa lọwọ wa, wọn ti kọkọ ṣe e lasiko ti iwọde n lọ lọwọ, lọjọ yẹn naa ni wọn kede ofin konile-gbele, ni bayii, wọn tun fẹẹ lo agbara le wa lori pe ki a ma kora wa jọ lati jiroro. Ohun ti mo mọ ni pe ijọba ko le pa wa lẹnu mọ.”

 

Leave a Reply