Nitori ọrọ ti ko to nnkan, Usman pa ọmọọya kan naa mẹta ni Ṣaki

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2022 yii nile-ẹjọ sun ẹjọ ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Abubakar Usman, to pa ọmọ iya kan naa mẹta lọjọ kan ṣoṣo bíi ẹni pẹran si.

Bii aja to ti ya digbolugi, tabi olongbo to ti ya ẹhanna la gbọ pe Usman huwa lọjọ naa, iyẹn Ọjọbọ Tọsidee, ọsẹ to kọja, ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, nigba to wo awọn tẹgbọn-taburo naa, Bello Abdulkadri, Ismail Abdulkadri ati Abdullahi Abdulkadri sunsun, to si ṣa wọn ladaa titi ti ẹmi fi bọ lara wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ naa lede aiyede kan bẹ silẹ laarin Usman pẹlu awọn tẹgbọn-taburo yii laduugbo Oke-Orogun, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, tọkunrin naa si tori ẹ pa awọn ẹni ẹlẹni bii ẹni pẹran.

Kayeefi to wa ninu iṣẹlẹ yii ni pe, ki i ṣe pe awọn mẹtẹẹta tọkunrin afurasi ọdaran naa pa ni wọn jẹ ọmọ kekere, ẹgbẹ loun pẹlu eyi to n jẹ Bello yẹn, nigba ti eyi Abdullahi jẹ ọmọọdun mẹtala ni tiẹ, ti Ismail si jẹ ọmọọdun mọkanla.

Awọn ọlọpaa ni wọn mọ bi wọn ṣe mu ọkunrin oniwa bii maaluu to ya were yii lẹyin tawọn ara adugbo Oke-Orogun nibẹ fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti.

L’Ọjọbọ, (Tọsidee), ni Sajẹnti ọlọpaa kan, Philips Amuṣan, wọ Usman dele-ẹjọ Majisireeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, fun ẹsun ipaniyan lorukọ CP Ngozi Ọnadeko ti i ṣe oga agba ọlọpaa ipinlẹ yii.

Onidaajọ Abimbọla Amọle-Ajimọti ko fun un lanfaani awijare kankan to fi paṣe pe ki wọn lọọ fi i pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo to wa niluu Ọyọ.

Ọ waa sun igbẹjọ ṣi ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2022 yii pẹlu ireti pe ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọyọ yii ti tọ ile-ẹjọ naa sọna lori ọna ti igbẹjọ ati idajọ yoo gba waye lori ẹjọ naa.

Leave a Reply