Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni gende-kunrin kan, Ọgbẹni Ridwan Akintunde, gun ọrẹ rẹ, Abeeb Saliu, pa ni agbegbe Baba Saka, Ọlọjẹ, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lasiko ti ede aiyede bẹ silẹ laarin wọn.
ALAROYE gbọ lẹnu ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe pe ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Abeeb atawọn ọrẹ rẹ n ṣe ipade, lasiko naa ni Abeeb ni ki Ridwan ba oun mu dẹsitọọpu rẹ, Ridwan yari pe oun ko ni i fun un, eyi lo fa gbọnmi-si i, omi-o-to-o laarin wọn. Niṣe ni Ridwan lọọ mu ọbẹ, lo ba gun Abeeb lọrun ati gbogbo ara. Wọn ko ti i gbe ọmọkunrin naa de ileewosan to fi dagbere faye.
A gbọ pe iyawo oloogbe ṣi wa ninu oyun oṣu mẹfa, ati pe oun nikan ni iya rẹ bi.
Ni bayii, Ridwan ati awọn mọlẹbi rẹ ti sa kuro nile, gbogbo ọna lati ri i mu lo ja si pabo.
Wọn ti gbe oku Abeeb lọ si yara igbokuu-si nileewosan jẹnẹra tilu Ilọrin, ti wọn si ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.
Awọn mọlẹbi oloogbe rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati awọn ọlọpaa pe awọn n fẹ idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa, tori pe ẹbi ẹni to pa wọn lọmọ lowo lọwọ, o si n fẹ ki wọn pana iṣẹlẹ naa mọlẹ.