Nitori ọrọ to sọ lori esi idibo to n lọ lọwọ yii, ijọba apapọ kilọ fun Ọbasanjọ

Jọkẹ Amori

Ọrọ ti aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, sọ lori eto idibo aarẹ ti wọn n ka lọwọ yii ti di wahala, ijọba apapọ si ti fun un lesi pe ki ọga ṣoja atijọ naa ma fi ọrọ ẹnu rẹ da wahala tabi ogun silẹ.

Lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ gbe iwe kan jade, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko idibo naa, ati bi INEC ṣe kọ lati fi ẹrọ igbalode gbe esi idibo sori ikanni wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣeleri.

Ninu ọrọ rẹ, Ọbasanjọ ni ọpọlọpọ owo ni ijọba na lati ri i pe eto idibo yii lọ bo ṣe yẹ ko lọ, bẹẹ ni wọn pese ohun gbogbo ti ajọ eleto idibo nilo fun wọn, ṣugbọn o jẹ ohun ijọloju pe gbogbo awọn ẹrọ ti wọn ti pese fun wọn lati mu ki eto idibo yii lọ lai si eru tabi wahala kankan ko ṣiṣẹ lasiko to yẹ ko ṣiṣẹ pẹlu bi awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo kan ṣe ti gba ẹyin bẹbọ jẹ, eyi to wa mu ko di ohun ti wọn n fọwọ kọ esi idibo ranṣẹ, dipo ki wọn fi i ranṣẹ sori ẹrọ ti yoo gbe e lọ si ori ikanni ajọ eleto idibo taara. Igbesẹ yii ni Ọbasanjọ ni o ti mu ki ọpọ kọwọ bọ esi ibo naa loju, to fi jẹ pe ọpọ esi idibo ti wọn gbe jade yatọ si ifẹ inu awọn oludibo.

Ọbasanjọ ni ọga INEC le sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa eyi o, ṣugbọn ko yẹ ko waa kawọ gbera lai ṣe ohunkohun, niwọn igba to mọ pe wọn ti kọwọ bọ esi idibo na loju pẹlu ọna ti wọn gbe e gba nitori bi awọn ẹrọ to yẹ ki wọn lo ko ṣe ṣiṣẹ.

Baba ti wọn tun maa n pe ni Ẹbọra Owu yii ni ko waa yẹ ka lo ọgbọn arekereke lati da wahala silẹ ni orileede nitori iwa wọbia, ailoootọ ati arekereke ti awọn kan lo lati gbowo fun awọn oṣiṣẹ eleto idibo lati jẹ ki wọn yi esi idibo naa sọdọ wọn atawọn ti wọn n gbowo ẹjẹ lọwọ wọn.

Ọbasanjọ ni niwọn bo ti jẹ pe ajọ eleto idibo ti sun eto idibo to ku ọjọ mẹrin siwaju ri, ko sohun to yẹ ko di wọn lọwọ lati wa ojutuu si awọn kudiẹ kudiẹ to n lọ lọwọ nipa eto idibo yii. O ni to ba jẹ pe ọwọ rẹ mọ, oun lo yẹ ko gba Naijiria lọwọ ewu ati ijamba to n rọ dẹdẹ loke yii. Aarẹ atijọ naa ni nibikibi ti ẹrọ to n gba esi idibo ateyi to n kọ orukọ awọn oludibo silẹ ko ba ti ṣiṣẹ, niṣe lo yẹ ki ajọ eleto idibo da iru ibo bẹẹ nu.

O waa gba Aarẹ Muhammadu Buhari nimọran lati ri i pe wọn fagi le awọn esi idibo ti ojoro ati arumọjẹ ba wa, ki wọn si dibo mi-in nibẹ lọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, nibi ti wọn yoo ti lo awọn ẹrọ idibo mi-in. Ọbasanjọ gba wọn nimọran pe alaga awọn agbẹjọro nilẹ wa ati aṣoju awọn ẹgbẹ oṣelu mẹrin to lorukọ ju, pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in le jokoo gẹgẹ bii igbimọ lati ri i pe eleyii di ṣiṣe.

Ṣugbọn ijoba apapọ ti ni ki aarẹ atijọ yii ma ṣe da ogun silẹ, pẹlu ọrọ to sọ sinu lẹta to kọ naa, eyi to fi n ti awọn eeyan nidii lati bẹrẹ wahala.

Minisita feto iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Muhammed lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Ṣẹgun Adeyẹmi, gbe jade lorukọ rẹ. O ni niṣe ni Ọbasanjọ fẹẹ fi lẹta to kọ yii bu ẹnu atẹ lu eto idibo naa, ko si ti awọn araalu lọpọn-pọn-ọn lati da wahala silẹ. Lai Muhammed ni o ya oun lẹnu pe ẹni to ti figba kan jẹ aarẹ orileede yii yoo maa pọn irọ ni beba, ti yoo si msa gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.

Lai Muhammed ran Ọnasanjọ leti pe eto idibo ti oun funra rẹ ṣe nigba to wa nipo buru ju eyi to n bu ẹnu atẹ lu yii lọ. O ni aarẹ tẹlẹ naa ko si ni ipo lati ma gba Aarẹ Buhari nimọran lati fi iranti rere silẹ nipa ṣiṣe eto idibo ti ko ni eru tabi wahala ninu ki ijọba rẹ too kogba sile.

Leave a Reply