Nitori ọti amu ju, ile-ẹjọ tu igbeyawo ka ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Gbogbo oriṣiiriṣii orukọ ti Abilekọ Dorcas pe ọkọ rẹ, Ọgbẹni Akinọla Faleye Samuel, lo ba a mu lakooko to waa jẹjọ lori ẹsun tiyawo ẹ fi kan an pe ọmuti paraku ni nitori niṣe lo n ta gọọ gọọ, ihuwasi rẹ nile-ẹjọ ọhun jọ ti ọmuti loootọ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii, lo di ẹlẹẹkẹta tawọn tọkọ-taya naa yoo fara han nile-ẹjọ lori ẹsun ọhun latari bi wọn ṣe n sun igbẹjọ wọn siwaju ni gbogbo igba.

Abileko Dorcas Akinọla lo mu ẹjọ ọkọ rẹ wa pe ki wọn ba oun tu igbeyawo wọn ka lai fakoko ṣofo.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni lati ọdun 2012 loun ti yago fun Samuel tori niṣe lo n mu ọti lile bii ẹni mu piọ wọta, to ba si ti yo tan bayii, alupamokuu lo maa n fi toun ṣe.

O ni alajangbila ẹda kan lọkọ oun, ko sẹni to le da a lẹkun ko gbọ lakooko to ba n lu oun lọwọ, eyi lo si mu ki oun kuro lọọdẹ rẹ nigba ti ilukulu ọhun fẹẹ gbẹmi oun, loun lọọ da gba ile, tori koto aye dara ju koto ọrun lọ.

Abileko Dorcas ni iyalẹnu lo tun jẹ foun pe ọkunrin naa tun le waa ka oun mọle lalẹ ọjọ kan, to si bẹrẹ si i ba oun ja pẹlu awọn ayalegbe ti wọn fẹẹ gba oun silẹ, to n dunkooko pe oun maa yọ windo yara oun sọnu ni. O ni baale ile naa ba a debii pe o lu aburo mama oun, ọsibitu lo si gba a silẹ. Bẹẹ lo tun fẹsun kan ọkọ rẹ pe ko jẹ koun foju kan awọn ọmọ oun to wa lakata rẹ.

Ọgbẹni Akinọla ko jẹ ki ọrọ ọhun tutu to fi ni igbeyawo  nilana ti Kristẹni loun ba iyawo oun ṣe, oun si ko ro pe ile-ẹjọ kekere lẹtọọ lati tu igbeyawo naa ka lai si awọn to tọwọ bọwe igbeyawo naa nikalẹ.

Adajọ M. A. Aworeni Ọladipupọ ni ohun ti wọn bi olujẹjọ yii kọ lo n dahun, niwọnbi ko si ti ri esi gidi kan fọ si ẹsun tiyawo rẹ fi kan an, ile-ẹjọ yoo tu igbeyawo ọhun ka.

Adajọ ọhun ni ile-ẹjọ ko laṣẹ lati gba awọn ọmọ to wa lakata ọkunrin naa pada fun olupẹjọ, o ni o le lọ sọfiisi itọju awọn ọmọ wẹwẹ (Welfare) to wa laduugbo wọn, o si paṣẹ fun tọkọ-taya naa lati ko iwe-ẹri igbeyawo wọn wa si kootu naa lọjọ mẹjọ, ki wọn le yanju ọrọ ọhun.

Leave a Reply