Nitori owo, Kamilu atọrẹ rẹ fẹẹ pa iya arugbo l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla. Oṣogbo

Awọn ọdọkunrin meji, Ọlagunju Kamilu ati Adenle Mujeem, ni wọn fara han niwaju ile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lori ẹsun pe wọn fẹẹ pa iya arugbo.

A gbọ pe inu ile kan naa lagbegbe Isosu, niluu Ẹdẹ, lawọn olujẹjọ n gbe pẹlu iya arugbo ti wọn pe orukọ rẹ ni Suleiman Fatimah yii.

Agbefọba, Inspẹkitop Akintade Jacob, ṣalaye pe lọjọ keji, oṣu keji, ọdun yii, lawọn mejeeji wọnu yara iya arugbo naa. Wọn gbiyanju lati pa a, ki wọn le ji awọn nnkan ini rẹ lọ.

Akintade sọ siwaju pe iwa ti wọn hu ta ko ipin okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516) ati ẹẹdẹgbẹta o le mẹsan-an (509) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Lẹyin ti awọn olujẹjọ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn, Sunday Abọlade Ismail, rọ kootu lati fun wọn ni beeli lọna irọrun. Bakan naa ni iya agba naa bẹ adajọ lati tu awọn ọmọ naa silẹ nitori wọn ti da bii ọmọ si oun.

Ṣugbọn Adajọ Ishọla Omiṣade sọ pe ki wọn lọọ fi awọn mejeeji sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun yii, tigbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply