Nitori owo, tẹgbọn-taburo gbimọ-pọ lati ji ọmọ ọga wọn gbe l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Miliọnu meji naira ni awọn tẹgbọn-taburo kan Blessing Oyeleke ati David Oyeleke, pẹlu ẹni kẹta wọn tiyẹn n jẹ Kabiru Oniyitan, n beere lọwọ ọga ti wọn ti ba ṣiṣẹ ri, wọn lawọn yoo ji ọmọ rẹ gbe to ba kọ lati sanwo naa si akanti awọn. Ohun to gbe wọn de tọlọpaa niyẹn.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kejila yii, lọwọ ọlọpaa tẹ wọn, lẹyin ti ọga wọn atijọ naa, Ọgbẹni Makinde Oluwatoyin, oludari ileeṣẹ kan l’Ọta, lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Onipanu, pe oun gba ipe ijaya kan latọdọ awọn kan ti wọn ni awọn yoo ji ọmọ oun ọkunrin torukọ ẹ n jẹ Solomon Makinde gbe lati ileewe rẹ, awọn yoo si pa gbogbo idile oun run, afi toun ba sare san miliọnu meji si akanti kan kọjọ mẹta too pe.

O ni awọn to pe oun naa ṣapejuwe ileewe ti Solomon wa, wọn si juwe ile oun paapaa bii pe awọn jọ n gbe ni. Eyi to fi han pe wọn ti wadii oun jinna.

Ifisun rẹ yii ni DPO Onipaanu atawọn eeyan ẹ, ṣiṣẹ le lori, ti wọn fi ri eyi to jẹ obinrin ninu awọn afurasi naa mu, ti wọn si ri foonu ti wọn fi n pe ipe ijaya naa lọwọ rẹ.

Blessing ti wọn ri mu yii lo ṣọna bi wọn ṣe ri awọn meji yooku mu, bo tilẹ jẹ pe DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ pe o ṣi ku ẹni kan ninu wọn ti ọwọ ko ti i ba.

Nigba ti wọn n ṣalaye idi ti wọn fi fẹẹ ji ọmọ ọga wọn tẹlẹ naa gbe, awọn mẹta tọwọ ba yii sọ pe awọn mọ pe ọga awọn yii lowo lọwọ, agbara rẹ ka miliọnu meji tawọn beere naa lawọn ṣe pe e lori foonu pe ko sanwo naa bi ko ba fẹẹ padanu ọmọ rẹ ọkunrin ati gbogbo idile rẹ.

Ẹka to n gbọ ẹjọ awọn ajinigbe ni CP Edward Awolọwọ Ajogun paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ fun itẹsiwaju ẹsun wọn.

Leave a Reply